It has been suggested that this article be merged with Àdàkọ:Pagelist. (Discuss) |
Lola Ogunnaike | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 13 Oṣù Kẹ̀sán 1975 New York City |
Orílẹ̀-èdè | American |
Iléẹ̀kọ́ gíga | New York University University of Virginia |
Iṣẹ́ | Journalist |
Employer | Arise News |
Olólùfẹ́ | Deen Solebo |
Àwọn ọmọ | 1 |
Lọlá Ògúnnáìkè jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tún jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà (American) tí ó jẹ́ amúlùúdùn àti oníròyìn ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà.
Wọ́n bí Lọlá ní ojo ketala osu kesan odun 1975 (September 13, 1975) ní ilú New York City àmọ́ àwọn òbí rẹ̀ méjèjì jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó jáde nílé ẹ̀kọ́ J.E.B. Stuart High School ní Fairfax, ìlú Virginia. Ó gba oyè ẹ̀kọ́-kejì nínú iṣẹ́ ìròyìn ní ilé-ẹ̀kọ́ àgbà ti New York University , nígbà tí ó ti kọ́kọ́ gba oyè ìmọ̀ àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ Lítíréṣọ̀ Gẹ̀ẹ́sì (English literature) nílé ẹ̀kọ́ àgbà University of Virginia.
Ògúnnáìkè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oníròyìn ní ọdún1999 nípa ṣíṣe ìròyìn amúlùúdùn àti àwọn àṣà míràn tó bá jẹ yọ. Bákan náà ni ó ń jábọ̀ ìròyìn fún ile iṣẹ́ ìròyìn ti New York Times tí ó sì jẹ́ ọ̀gá ní ẹ̀ka ìròyìn amúlùúdùn tí ó ń ṣe pẹ̀lú bí ó ṣe dajú kọ àwọn olórin ilè Amẹ́ríkà ọlọ́kan ò jọ̀kan bíi: Jennifer Lopez, Ozwald Boateng, Oprah Winfrey, tí ó sì ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ kóríyá nípa "Àṣà àti Ìsinmi" lápá kan inú ìwé ìròyìn náà. Bákan náà ló tún jẹ́ akọ̀ròyìn fún ìwé ìròyìn "Vibe magazine", ní èyí tí ó fi ń dá sí àwọn ìròyìn olóṣooṣù nípa orin àti àwọn ìròyìn tó jẹ mọ́ tàwọn ọ̀kọrin gbogbo. Ó sì tún kọ ìròyìn fún ìwé ìròyìn bíi: Rolling Stone, New York, Glamour, Details (magazine), Nylon, "New York Observer" àti "V Magazine". Ó sì tún wà lára àwọn ikọ̀ tí ó fọ̀rọ̀ wá aya olórí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà tẹ́lè ̣rí lẹ́nu wò ìyẹn: Michelle Obama lórí àbẹ̀wò rẹ̀ sí orílẹ̀ èdè South Africa. Lọlá tún jẹ́ ajábọ̀ ìròyìn fún "New York Daily News","NOW," "Rush, lórí ìròyin pàjáwìrì tí ó jẹ mọ́ ti amúlùud́ùn àti "Molloy" bákan náà ni ó tún jẹ́ ajábọ̀ ìròyìn fún ilé iṣẹ́ agbóhùn sáfẹ́fẹ́ ti CNN’s “American Morning"[1] níbi tí ó ti ṣiṣẹ́ láti ọdún 2007 tí tí di 2009.[2][3]
Lọlá ti hàn lórí àwọn ètò ọlọ́kan ò jọ̀kan orí ẹrọ amóhùn-máwòrán bíi: NBC’s today Show, MTV àti VH1. Wọ́n kàá ní oṣù karùn ún ọdún 2007 (May 2007) mọ́ àwọn obìnrin aláwọ̀ dúdú tí ó nípa jùlọ ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà (Ebony’s ‘150 Most Influential Blacks in America”). Lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí, òun ni ó dá Arise Entertainment 360 sile
Òun ni ìyàwó fún Deen Ṣólebọ, tí wọ́n sì bí ọmọ ọkùnrin kan ṣoṣo.[4][5]
"Lola Ogunnaike's Official website". Archived from the original on 2018-08-19. Retrieved 2018-05-14.