Mai Mala Buni | |
---|---|
Governor of Yobe State | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga 29 May 2019 | |
Deputy | Idi Barde Gubana |
Asíwájú | Ibrahim Geidam |
Caretaker Chairman of the All Progressives Congress | |
In office 25 June 2020 – 22 March 2022 | |
Asíwájú | Adams Oshiomhole |
Arọ́pò | Abdullahi Adamu |
National Secretary of the All Progressives Congress | |
In office 14 June 2014 – March 2019 | |
Asíwájú | Tijjani Tumsah |
Arọ́pò | Victor Giadom |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 19 Oṣù Kọkànlá 1967 Gujba, North-Eastern State, Nigeria (now in Yobe State) |
Ọmọorílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | All Progressive Congress |
Residence | Yobe, Nigeria |
Alma mater |
|
Occupation | Politician |
Mai Mala Buni Àdàkọ:Post-nominals tí wọ́n bí ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kọkànlá ọdún 1967 jẹ́ olóṣèlú tí ó ti ṣe gómìnà eí ní ìpínlẹ̀ Yobe] ní ọdún 2019 ati ọm9 lrílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2][3][4]Òun noi wọ́n dìbò yàn nínú ìdìbò tó wáyé ní ọdún 2019 lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress.[5][6] Ṣáájú kí ó di gómìnà ni ó tinwà nípò Akọ̀wé àgbà fún ẹgbẹ́ òṣèlé náà.[7][8]
Wọ́n bí Buni ní ọjọ́ kọkàndínlógún òṣù kọkànlá ọdún 1967 ní agbègbè Bínú Gàrí ní Ìpínlẹ̀ Yobe .[9]Bínú bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ ìkẹ́kọ́ ilé-kéu láti kọ́nípa ìmọ̀ Àlùkùránì lábẹ́ olùkọ́ rẹ̀ tí ó tún jẹ́ bàbá rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Buni Gari níbi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1979. Ó wọlé ẹ̀kọ́ oníwé mẹ́wá ti ìjọba tí ó wà ní Goniri ní ọdún 1979, lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, tí ó jáde gbàwé ẹ̀rí ìwé mẹ́wá ní ọdún 1985.[10] Buni tún wọlé ẹ̀kọ́ Fásitì Espan Formation tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Benin Republic láti kò nípa ìmọ̀ International Relation tí ó sì jáde ní ọdún 2014. [11] Nìkan náà ni ó gba ìwé ẹ̀rí Master láì ilé-ẹ̀kọ́ Leeds Beckett University, ní United Kingdom.ọjọ́
Látàrí ìmọ̀ nípa iṣẹ́ Irinkerindo ọkọ̀, tí jẹ́ iṣẹ́ kan pàtàkì nínú ẹbí rẹ̀ ni ó jẹ́ kí ó tètè ji gìrì sí òwò síṣe. Èyí mu kí ó lọ kẹ́kọ́ọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ nílé ẹ̀kọ́ iṣẹ́ ọwọ́ ti College of Vocation Science and Technology níbi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí dípúlọ́mà ní ọdún 2012.
Mai Mala Buni jẹ́ Alága fún àwọn ilé-iṣẹ́ wọ̀nyí:
Mala Buni bẹ̀rẹ̀ ìṣèlú rẹ̀ ní ọdún 1992 nígbà tí díje dupò lábẹ́ àbùradà ẹgbẹ́ òṣèlú National Republican Convention (NRC) láti sojú fún ẹkùn Buni lábẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ Gujba Local government council. Wón sì yanán gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ fún ìgbìmọ̀ náà. Ó di amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ aṣòfin àgbà ní National assembly ní ọdún 2000, àti ọdún 2004 tí wọ́n yanán gẹ́gẹ́ bí adarí fún ìgbìmọ̀ University of Uyo.
Ní ọdún 2006, wọ́n dìbò yànán gẹ́gẹ́ bí Alága Advanced Congress of Democrats ní Ìpínlẹ̀Yobe. Ní ọdún 2007, wọ́n darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Action Congress látinú ẹgbẹ́ ìṣèlú Advanced Congress of Democrats kí ẹgbẹ́ Action Congress lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin. Ẹgbẹ́ náà yàná. Wọ́n yanán láìfọ̀tápè gẹ́gẹ́ bí Alága ẹgbẹ́ ìṣèlú tuntun náà Action Congress party tí wọ́n sì dìbò yàná ẹ́gẹ́ bí Alága gbogbo gbò láti ọdún 2007 sí 2010. Buni darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ìṣèlú All Nigeria Peoples Party (ANPP) ní ọdún 2011 ní Ìpínlẹ̀ Yobe tí wọ́n sì yànán gẹ́gẹ́ bí olùbádámọ̀ràn pàtàkì sí gómìnà Ìpínlẹ̀ Yobe Ibrahim Gaidam lórí ètò ìṣèlú àti ìṣòfin. Ní ọdún 2013, tí wọ́n da àwọn ẹgbẹ́ ìṣèlú papọ̀ láti da ẹgbẹ́ ìṣèlú All Progressives Congress (APC),[9][12] Wọ́n fi Mai Mala Buni ṣe akọ̀wé ẹgbẹ́ ọ̀hún ní ìpínlẹ̀ Yobe tí Won sì padà yànán gẹ́gẹ́ bí Alága àgbà ẹgbẹ́ ọ̀hún ní ìpínlẹ̀ Yobe. Mai Mala Buni di Akọ̀wé agba fún ẹgbẹ́ ìṣèlú APC tí wọ́n dìbò yàn ánọ́kọ́ fún ẹgbẹ́ ìṣèlú náà ní ọdún 2014. [13] Lásìkò tí ń ṣiṣẹ́ bí Akọ̀wé àgbà yí ni wọ́n dìbò yan Muhammadu Buhari gẹ́gẹ́ Ààrẹ Nàìjíríà ní ọdún 2015. Látarí ìfarajìn rẹ̀ fún ẹgbẹ́ ni wọ́n tún ṣe yànán sípò Akọ̀wé Àgbà ẹgbẹ́ ìṣèlú náà lẹ́ẹ̀kejì ní ọdún 2018.[9] Pẹ̀lú ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Akọ̀wé àgbà ẹgbẹ́ ìṣèlú APC ati Alága ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ Nigeria Shippers council, wọ́n yànán kí ó wá ṣe adíje dupò gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Yobe lábẹ́ ẹgbẹ́ ìṣèlú APC ní ọdún 2019.[14] Nínú ìdìbò gbogbo gbo ọdún 2019, wọ́n dìbò yàn án gẹ́gẹ́ bí gómìnà kẹrin ní ìpínlẹ̀ náà lẹ́ni tí ó jáwé olúborí pẹ̀lú ìbò tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ri ati ọgbàọ́rinlé mẹ́rin ati mẹ́talá nígbà tí alátakò rẹ̀ láti inú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP Alhaji Bello Ìfòyà ní ìbò ẹgbẹ̀rún márùdínlọ́gọ́rún ati 73 ìbò péré. [15] Wọ́n tu ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ ìṣèlú APC ka ní inú osù Kẹfà ọdún 2020, àmọ́ nígbà tí wọn yóò tun tò, Mai Mala Bunini wọ́n fi ṣe Alàga Àgbà yányán fún ẹgbẹ́ òṣèlú náà ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Buni sì ni ẹni akọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ ṣe àpérò gbogbo gbò fún ẹgbẹ́ náà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [16] Ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe yí ni wọ́n mojú tó ìgbòkègbodò ẹgbẹ́ náà fún odidi òṣù mẹ́fa ṣáájú kí wọ́n tó ṣe àpérò gbogbo gbò ọ̀hún.
Wọ́n sún àsìkò tí ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe ẹgbẹ́ yí lábẹ́ adarí Buni siwájú si fún oṣùn mẹ́fà nínú ìpàdé ìgbìmọ̀ kan tí eọ́n ṣe ní ọjọ́ kája oṣù Kejìlá ọdún 2020 [17]
Mai Mala Buni sọ wípé: "Ìjọba wa yóò mú sapá láti ri wípé ọwọ́ ajọ Universal Basic Education Commision (UBEC) tẹ owó ìrànwọ́ lásìkò, láti lè jẹ́ kí ètò ẹ̀kọ́ kẹ́sẹjárí fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Bákan náà ni a ó gbìyànjú láti kọ́ àwọn iyàrá ìgbẹ̀kọ́ tuntun, a ó gba àwọn olùkọ́ tuntun tó dántọ́, tí a ó sì pèsè àwọn ohun amáyédẹrùn fún àwọn olùkọ́. Bákan náà ni a ó pèsè ohun ìgbẹ̀kọ́ tí yóò mú ẹ̀kọ́ rọrùn fún àwọn olùkọ́ ati akẹ́kọ̀ọ́ láti lè fakọyọ bíi tàwọn akẹgbẹ́ wọn lágbàáyé. Bákan náà ni a ó ti ṣe nílé ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ndìrì gbogbo. A ri wípé ètò ẹ̀kọ́ fanimọ́ra, wuyì kí ó lè ṣiṣẹ́ tí a ran. Sísan owó ìdánwò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò tẹ̀ siwájú bíi ti àtẹ̀yìnwá kí àwọn òbí ati alágbàtọ́ lè nífẹ́ọ̀kànbalẹ̀ lórí owó ẹ̀kọ́ sísan ní ìpínlẹ̀ Yobe. Láti lè ri wípé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà fọkàn sí ẹ̀kọ́ wọn, a ó bá ìjọba apápọ̀ ní ìbáṣepọ̀ tà pinminrin lórí fífún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní òúnjẹ nílé ẹ̀kó wa gbogbo. "[18] Lábẹ́ ìṣàkóso Buni, ìjọba rẹ̀ ti na owó tí ó tó 2.1 billion títí di oṣù kẹrin ọdún 2020 láti fi kọ́ ilé-ẹ̀kọ́ ìgbàlódé méje ní àwọn agbègbè orísiríṣi ní Ìpínlẹ̀ Yobe.[19] Àtojúsùn ìgbésẹ̀ yí ni láti dí apọ̀jù akẹ́kọ́ kù nínú àwọn ilé-ẹ̀kọ́ wọn gbogbo. Ìpínlẹ̀ Yobe wà lára àwọn ìpínlẹ̀ tí àwọn agbésùnmọ̀mí Boko Haram ti ṣọṣẹ́ jùlọ. Gómìnà Mai Mala Buni ti da àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ ogúnléndé tí wọ́n gbé ní agọ́ ogúnléndé padà sílé wọn tí ó sì tún fi àwọn ohun amáyédẹrùn pẹ́pẹ̀pẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Ìjọba ìpínlẹ̀ náà pẹ̀lú ìbáṣepọ̀ ilé ìfowó-pamọ́ onídàgbà-sókè African Development Bank lábẹ́ Agro-Processing, Productivity Enhancement, and Livelihood Improvement Support, APPEALS, Project ni wọ́n ti ṣe ìrànwọ́ fún àwọn ènìyàn náà tí wọ́ do ẹgbẹ̀rún márùún níye.
Ìjọba rẹ̀ náà tún kọ́ ilégbèé fún àwọn ogúnléndé ní inú oṣù kẹsàán ọdún 2020. Iṣẹ́ àkànṣe yí ni ilé-iṣẹ́ elépo Nigerian National Petroleum Corporation (NNPC), Shell Petroleum Development Company of Nigeria Limited (SPDC) Joint Venture (JV), Shell Nigeria Exploration and Production Company Limited (SNEPCO) àti Total Nigeria Plc. ṣe agbátẹrù rẹ̀ pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Ìjọba Ìpínlẹ̀ Yobe [20]
Ní agbami ti ètò ìlera, ìjọba rẹ̀ ti kọ́ ilé-ìwòsan tí ó ní ilé ayẹ̀wò mẹ́tàléláàdọ́ta nínú ọgbàọ́rúnléméjìdínlọ́gọ́jọ tí ó ṣèlérí rẹ̀ fún ará ìlú, àwọn ilé-ìwòsan náà ni wọn yóò ma ṣe ayẹ̀wò fún àwọn aláìsàn tí wọn yóò sì ma fún wọn ní oògùn lọ́fẹ́, ó tún kọ́ ilé ìgbé fún àwọn takọ-tabo oníṣẹ́ ìlera nínú àwọn ilé-ìwòsan yí gbogbo kí wọ́n lè ma tọ́jú àwọn ènìyàn nígbà gbogbo tí wọ́n bá yọjú.
Lágbọ́nrin ti ilégbèé, ìjọba rẹ̀ ti kọ́ ilé tí ó ẹgbẹ̀rún kan ó lé lọ́gọ́jọ láàrín ọdún méjì akọ́kọ́ tí ó gbàṣèjọba. Bákan náà ni ó tún fẹ́ ṣe nínú apákejì ìṣèjọba rẹ̀. [21]
Ó gba amì-ẹ̀yẹ ìdánilọ́lá ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ìyẹn Commander Of The Order Of The Niger (CON) ní inú osù Kẹwàá ọdún 2022 láti ọwọ́ Ààrẹ àná Muhammadu Buhari.[22]