Majek Folabee Shamsudeen | |
---|---|
Orúkọ àbísọ | Majekodunmi Fasheke |
Ọjọ́ìbí | February 1949 Benin Edo State, Nigeria |
Irú orin | Reggae, roots reggae, rock |
Occupation(s) | singer, songwriter, actor |
Years active | early 90s—present |
Labels | Interscope Records |
Associated acts | Jastix Monicazation |
Majekodunmi Fasheke, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Majek Fashek jẹ́ olùkọ orin, atajìtá àti olórin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2] Ó di ìlú-mọ̀ọ́ká olòlórin ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní àsìkò ọdún 1988, fún àwo orin rẹ̀ tí ó gbé jáde lásìkò yí tí ó pè ní _Onígbèkùn ọkàn (Prisoner of Conscience), àti àwọn orín rẹ̀ ọlọ́kan ò jọ̀kan bíi : Send down the rain àti bẹ̀è bẹ̀è lọ tí ó gha àwọn àmì ẹ̀yẹ òmìdáni lọ́lá oríṣríṣi. [3] Ẹ̀wẹ̀, Majek ti ṣeré pọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣèré olórin oríṣríṣi ìlú mọ̀ọ́ká bíi: Tracy Chapman, Jimmy Cliff, Michael Jackson, Snoop Dogg, àti Beyoncé.[4][5]
Wọ́n bí Fashek ní ìlú Benin tí ó jẹ́ olú ìlú fún to an Ìpínlẹ̀ Edo níbi tí ìyá rẹ̀ ti wá, tí bàbá rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ ìlú Ìjẹ̀ṣà.[1][2] Fashek yan ìlú Benin láàyò lọ́dọ̀ ìyá rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí bàbá àti ìyá rẹ̀ kọ ara wọn sílẹ̀, tí ó sì dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ akọrin ìjọ Aládùúrà kan, níbintí ó kọ́ bí wọ́n ṣebń lu ìlú àti àwọn ohun èlò orin mìíràn, tí ó sì ń hun orin fún àwọn akọrin ìjọ náà.[6]
Nípa torin, a lè sọ wípé Majek ni àrólé fún olóògbé Bob Marley, nítorí gbogbo ìwọ́hùn olóògbé náà ni Fashek mú pátá.[7][8] Ó wà lára ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ọmọ bíbí ilẹ̀ [Nàìjíríà]] tí gbé orin Reggae tí ó ti ilẹ̀ Caribbean wá. Àmọ́, kàkà kí Majek ó gbàgbé ilé àti orin ìbílẹ̀ wa pátá, ń ṣe ló mú ọnà orin bíi Fújì àti Jùjú mọ́ orin reggae tí ó sì tibẹ̀ fa ọnà orin tirẹ̀ tí ó pè ní ''Kpangolo'' yọ lọ́nà arà.[9][10]
Majek kú sí ojú orun rẹ̀ ní ọjọ́ kejì oṣù Kẹfà ọdún 2020 sí ìlú New York.
|url=
value (help). AllMusic. Retrieved 1 October 2010.