Mary Lazarus | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Mary Lazarus 5 Oṣù Kàrún 1989 Abia State, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Ibadan |
Iṣẹ́ |
|
Ìgbà iṣẹ́ | 2002–Present |
Màríà Lásárù (tí a bí ní ọjọ́ karùn ún oṣù karùn ún ọdún 1989)[1] jẹ́ òṣèré àti ò ǹṣe fiimu ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni ó gba àmì ẹ̀yẹe lórí fiimu àwọn ènìyàn ìlú fún òṣèré tí ó ní ìlérí tí ó dára jùlọ ní ibi ẹ̀buǹ eré ìdárayá ti i àwọn ènìyàn ìlú (City People Entertainment Awards) ti odun 2018[2], wọ́n sì tún yàn án gẹ́gẹ́ bí i òṣèré tí ó dára jùlọ nínú ipa olùdarí ní ọdún kanná àn níbi ayẹyẹ ẹ̀bùn fún àwọn òṣèré Nollywood tí ó dára jùlọ (Best of Nollywood Awards).[3]
Lásárù wá làti Ìpínlẹ Abia ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìpínlẹ Abia wà ní agbègbè gúúsù ìla oorun ti oríl̀ẹ̀-èdè Nàìjíríà níbi tí ó jẹ wípé àwọn ẹ̀yà Ìgbò ni wọ́n wà níbẹ̀. Ukwa tí ó wà ní Ìjọba Ìbílẹ̀ ìla-oorun ní Ìpínlẹ̀ Abia gangan ni Lásárù ti wá. Ìdílé ẹlẹ́ni mẹ́sàn án ni a bí Lásárù sí èyí tí ìyá, bàbá pẹ̀lú àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ wa. Ó jẹ́ ìbejì nínú ẹbí yi àti wípé òun àti èkejì rẹ, Joseph tí ó jẹ́ ọkùnrin ni wọ́n bí gbẹ̀yìn.[4] Nígbà tí Lásárù ti lọ sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti ti girama tí ó sì ti gba ìwé ẹ̀rí moyege ní pàtàkì ti girama (West African Senior School Certificate), ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ti Ìbàdàn (University of Ibadan) níbi tí ó ti kọ́ ẹ̀kọ́ gba ìwé ẹ̀rí tí ó múnádóko lórí i Àlà-ilẹ̀ (Geography).[5][6]
Lásárù tí ó jẹ́ olókìkí jùlọ nínú àwọn ipa tí ó ti kó nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fiimu ti Nollywood, ó ṣe ìṣàfihàn akọ́kọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí i aláwòṣe ní ọdún 2002 kí ó tó wa darí lọ sí ilé-iṣẹ́ fiimu ti Nàìjíríà ní ọdún 2009 pẹ̀lú fiimu kan tí àkọlé rẹ ń jẹ́ "Waiting Years". Lásárù rí ipa kan kó nínú fiimu yi látipasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ Gbenro Ajibade ẹni tí ó ṣàfihàn rẹ sí John Njamah, ẹni tí í ṣe olúdarí fiimu yi tí ó sì tún wá fún un ní ipa tí yíò kó nígbẹ̀yìn nínú fiimu tí a ti dárúkọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Lásárù darí ìṣàfihàn fiimu kan tí àkọlé rẹ ń jẹ́ "Dance To My Beat", èyí tí ó tún gbé jáde ní ọdún 2017.
Lásárù gẹ́gẹ́ bí i aláwòṣe ti fi arahàn nínú oríṣiríṣi àwọn ìkéde ti ilé-iṣẹ́ Airtel àti MTN ti ṣe.
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn oníròyìn ti ìwé ìròyìn Vanguard, Lásárù dárúkọ ọmọtọla Jalade Ekeinde àti Jọkẹ Silva tí wọ́n jẹ́ gbajúgbajà òṣèré Nollywood gẹ́gẹ́ bí i àwọn tí òún ń wò kọ́ ìṣe wọn nínú iṣẹ́ fiimu ní Nàìjíríà. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò míràn àn pẹ̀lú àwọn oníròyìn ìwé ìròyìn The Punch, Lásárù dárúkọ òṣèré bìnrin ọmọ ilé Amẹ́ríkà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kimberly Elise gẹ́gẹ́ bí i ọ̀kan lára àwọn tí òún fẹ́ràn nítorí àwọn iṣẹ́ rẹ tí ó ti gbòòrò.[7]
Lásárù wá láti ìdílé ẹlẹ́ni mẹ́sàn án. Ìbejì ni Lásárù. Òun àti ìkejì rẹ tí ó jẹ́ ọkùnrin ni wọ́n jẹ́ àbígbẹ̀yìn ìya wọn. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn oníròyìn ti ìwé ìròyìn The Punch, ó ṣàpèjúwe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i ẹnìkan tí ó fẹ́ràn ìgbádùn.
|url=
value (help). Nigeria News (News Reader). 2020-10-16. Retrieved 2020-10-16.