Matilda Obaseki |
---|
Ọjọ́ìbí | 19 March 1986 Benin City |
---|
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
---|
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian |
---|
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Benin |
---|
Iṣẹ́ | Film Actress and Scriptwriter |
---|
Ìgbà iṣẹ́ | 2007-till present |
---|
Notable work | Tinsel |
---|
Olólùfẹ́ | Arnold Mozia |
---|
Àdàkọ:Use Nigerian English
Matilda Obaseki jẹ́ òṣèrébìnrin àti akọ̀tàn ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni olú ẹ̀dá-ìtàn nínú fíìmù orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Tinsel.[1]
Wọ́n bí Obaseki ní 19 March 1986 ní Benin City, ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Oredo ní Ipinle Edo níbi tí ó dàgbà sí. Òun ni àbígbẹ̀yìn láàrin ọmọ méje.[2][3]
Obaseki fẹ́ Arnold Mozia ní ìlú Benin, ní ọjọ́ 21 September, ọdún 2013. Èyí wáyé lẹ́yìn ìgbà tó bí ọmọ àkọ́kọ́ rẹ̀ ní 31 August 2012. Ó bí ọmọ ẹlẹ́ẹ̀kejì rẹ̀ ní 1 January 2015.[4][5][6]
Obaseki dàgbà sí ìlú Benin, níbi tí ó ti ṣe ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ àti gírámà rẹ̀. Ó dẹ́kun ẹ̀kọ́ rẹ̀ nínú ìmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní University of Benin láti dojú lé iṣẹ́ tíátà.[7]
Obaseki bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà ní ọdún 2007, àmọ́ ó di gbajúmọ̀ fún ìkópa rẹ̀ nínú fíìmù Tinsel, níbi tó ti ṣeré gẹ́gẹ́ bí i Angela Dede.[8] Kí ó tó kópa nínú fíìmù Tinsel,ó farahàn gẹ́gẹ́ bí i ọmọ-ọ̀dọ̀ nínú fíìmù orílẹ̀-"èdè America kan.[9] Fíìmù àkọ́kọ́ rẹ̀ ni fíìmù ọdún 2014 kan tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ A Place in the Stars, níbi tó ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Gideon Okeke àti Segun Arinze. Ó sì tún farahàn nínú getting over Him pẹ̀lú Majid Michel.[10]
- ↑ "I am living up my dream Tinsel cast — Matilda Obaseki". Encomium.com. Lagos: Encomiums Ventures Ltd. 27 December 2015. Archived from the original on 24 April 2016. Retrieved 7 May 2016.
This story was first published in ENCOMIUM Weekly on 22 October 2013.
- ↑ "Why I keep away from men Tinsel star, Matilda Obaseki". Modern Ghana. September 17, 2009. Retrieved March 19, 2016.
- ↑ "Matilda Obaseki Biography". Manpower Nigeria.
- ↑ "Photos - Tinsel Actress Matilda Obaseki White & Traditional Wedding - MJ Celebrity Magazine". MJ Celebrity Magazine. Retrieved 19 March 2016. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ Tayo, Ayomide O. (2 October 2015). "Matilda Obaseki: Actress shares loving picture of her family on Independence Day". pulse.ng. Archived from the original on 28 March 2016. Retrieved 19 March 2016.
- ↑ "Matilda Obaseki Welcomes 2nd Baby Boy". Nigerian Entertainment Today. Retrieved 19 March 2016.
- ↑ Akutu, Geraldine (5 August 2018). "‘I Have No Regret Going Into Acting’". The Guardian (London, England: Guardian Media Group). Archived from the original on 27 April 2023. https://web.archive.org/web/20230427203318/https://guardian.ng/life/film/i-have-no-regret-going-into-acting/.
- ↑ "Matilda Obaseki Biography – Age, Wedding". MyBioHub.
- ↑ "8 Things You Probably Didn't Know about Matilda Obaseki". ConnectNigeria. 11 August 2016. Archived from the original on 12 June 2021. Retrieved 30 September 2023.
- ↑ BellaNaija.com (2018-01-15). "Must Watch Trailer! Majid Michel, Deyemi Okanlawon, Matilda Obaseki star in "Getting Over Him"". BellaNaija (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-08-02.