Muḥammad Mazhar Nanautawi (1821–1885) fìgbà kan jẹ́ onímọ̀ Mùsùlùmí ti orílẹ̀-èdè India àti àjà fétò òmìnira tó kópa pàtàkì nínú ìdàgbàsókè Mazahir Uloom. Ó kópa nínú Battle of Shamli[1][2].
A bí Muḥammad Mazhar sínú ìdílé Siddiqi family of Nanauta ní ọdún 1821.[3][4] Bàbá rẹ̀ Lutf Ali tán mọ́ Mamluk Ali Nanautawi.[5] Mazhar ṣe àkàsórí ìwé Kùráànì, ó sì gboyè ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ lọ́wọ́ bàbá rẹ̀.[4] Ó kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú Mamluk Ali Nanautawi ní ilé-ìwé girama ti Delhi College.[3] Ó tún kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú Muwatta Imam Malik pẹ̀lú ìmọ̀ àwọn ìwé hadith mìíràn pẹ̀lú Shah Abd al-Ghani Dehlawi àti Sahih Bukhari àti Shah Muḥammad Ishāq Dehlawi.[6] Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rashid Ahmad Gangohi ní Sufism.[7]
Wọ́n yan Mazhar sípò olùkọ́-àgbà ti ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ Arabic ní Government College ní Varanasi láti ọwọ́ Aloys Sprenger.[8] Ó padà di olórí ẹ̀ka Arabic department ti Government College, Ajmer.[9] Ó jẹ́ olùkọ́ ní ilé-ìwé Agra College.[10] Mazhar kópa nínú ìjà-fómìnira ti orílẹ̀-èdè India, ó sì jà pẹ̀lú Imdadullah Muhajir Makki ní Battle of Shamli.[11] Èrò rẹ̀ nípa ṣíṣe iṣẹ́ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ ìjọba yí padà ní ọdún 1857.[12] Ó dára pọ̀ mọ́ Nawal Kishore Press, ó sì ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi olóòtú, ó sì ṣiṣẹ́ fún ọdún méje.[13] Àwọn iṣẹ́ tó ṣe olóòtú fún ni iṣẹ́ Al-Ghazali, tí ń ṣe Ihya al-Ulūm àti Tāhir Patni's Majma' al-Bahhār; èyí tó padà di ìwé ètò ẹ̀kọ́ nígbà náà.[13] Ní oṣù kejì, ọdún 1867, Mazhar dara pọ̀ mọ́ Mazahir Uloom; níbi tí ó ti kọ́ ẹ̀kọ́ bíi tafsir, hadith, fiqh, ìwé lítíreṣọ̀ àti ìwé ìtàn.[14][15] Òun ni olùdásílẹ̀ Mazahir Uloom, ó sì rí sí ìdàgbàsókè rẹ̀.[7]
Mazhar kú ní ọjọ́ kẹta, oṣù kẹwàá, ọdún 1885.[16] Díẹ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ni Muhammad Qasim Nanautawi àti Khalil Ahmad Saharanpuri.[17]
Khan, Syed Aḥmad. "Mawlvi Muḥammad Mazhar Marhūm". In Shahjahānpuri, Abu Salmān (in ur). Tadhkira Khānwāda-e-Waliullāhi. Jamshoro: University of Sindh. pp. 513–519.
Muḥammad Shāhid Sahāranpuri. Deobandi, Nawaz. ed (in ur). Sawaneh Ulama-e-Deoband. 1 (January 2000 ed.). Deoband: Nawaz Publications. pp. 495–504.