Milka Irene Soobya | |
---|---|
Ìbí | 1989 (ọmọ ọdún 35–36) Buwenge, Jinja, Uganda |
Iṣẹ́ |
|
Milka Irene Soobya jẹ́ òṣèré àti òṣèlú ní orílẹ̀ èdè Uganda tí ó gbajúmọ̀ fún ipa Monica tí ó kó nínú eré Deception àti ipa Fifi Aripa nínú eré Power of Legacy. Ó díje fún ipò ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ aṣojú fún àwọn obìnrin fún Ìlú Jinja.[1][2]
Eré àkọ́kọ́ tí Soobya má ṣe ní eré Makutano Junction. Ó di gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bí eléré nígbà tí ó ṣe Monica nínú eré Deception tí ó ṣe láti inú ọdún 2013 títí di 2016.[3][4] Ó ti kópa nínú àwọn eré bíi The Rungu Girls, Honeymoon is Exaggerated, Christmas in Kampala and Taxi 24 èyí tí Akpor Otebele ṣe adarí fún. Ní ọdún 2018, ó kópa nínú eré Power of Legacy gẹ́gẹ́ bí Fifi Aripa.[5] Ní ọdún 2020, ó díje fún ipò aṣojú àwọn obìnrin amọ̀fin ní ìlú Jinja.[6]
Ọdún | Àkọ́lé | Ipa tí ó kó | Àfíkún |
---|---|---|---|
2013 -2016 | Deception" | Monica | Lead role |
2016 | Christmas in Kampala | Christmas film | |
The Rungu Girls | |||
Honeymoon is so Exaggerated | |||
Taxie 24 ug | |||
2016 - to-date | Family Affairs | Herself – Co-host | Talk Show on Spark TV |
2018 | Power of Legacy | Fifi Arripa | Television series, main cast |
Wọ́n bí Soobya sí ìlú Jinja. Bàbá rẹ̀ ní Lt. Colonel Samuel Kafude, orúkọ ìyá rẹ sí jẹ́ Capt. Namutebi Agnes Mbuga. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Mbodo High School àti Mariam High School kí ó tó tẹ̀ síwájú sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Kyambogo University níbi tí ó tí gboyè nínú ìmò Procurement and Logistics Management.[7]