Moshood Abiola Polytechnic | |
---|---|
![]() Abawọle Moshood Abiola Polytechnic, Abeokuta, ipinlẹ Ogun | |
Established | 1980 |
Type | Public |
Rector | Dr. Adeoye Odedeji |
Location | Abeokuta, Ogun State, Nigeria |
Website | www.mapoly.edu.ng |
Moshood Abiola Polytechnic, tí a tún mọ̀ sí MAPOLY, jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga ní Abẹ́òkúta, Ìpínlẹ̀ Ògùn, Nàìjíríà. Àgọ́ Ojere, tí ó ní tó 960 hectares, wà ní apá gúúsù-ìlà Oòrùn Abẹ́òkúta, tí odò Ògùn ti yí ká láti apá gúúsù. Wón sọ́ lorukọ lẹ́yìn Moshood Kashimawo Olawale Abiola, ẹni tí wọ́n dìbò yàn gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Nàìjíríà ní ọdún 1993, ṣùgbọ́n wọ́n kò jẹ́ kí ó wá sí ọ̀fìsì.[1] Lẹ́yìn ikú MKO Abiola, ẹni tí ó jẹ́ alágbára tó pọ̀ jùlọ fún ilé-ẹ̀kọ́ náà ní ọdún 1998, ni wọ́n yíì orúkọ́ ilé-ẹ̀kọ́ náà sí Moshood Abiola Polytechnic, Abẹ́òkúta.[2][3]
Ilé-ẹ̀kọ́ gíga náà ni wọ́n dá sílẹ̀ ní kedere ní ọdún 1980 gẹ́gẹ́ bí Ogun State Polytechnic ní àkókò ìṣàkóso ọmọ ogun Harris Eghagha. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ràn fún ilé-ẹ̀kọ́ gíga náà ni Brigadier Harris Eghagha ṣe, ìjọba Chief Olabisi Onabanjo ni ó mú lọ́ọ̀.[citation needed][4] Ilé-ẹ̀kọ́ gíga náà bẹ̀rẹ̀ ní àgọ́ méjì, Oke-Egunya àti Onikolobo, ṣùgbọ́n ó kó lọ sí àgọ́ Ojéré láàárín oṣù kẹrin ọdún 1985 àti oṣù kẹta ọdún 1988.
Lọwọlọwọ, ilé-ẹ̀kọ́ gíga náà ní ẹ̀ka márùn-ún, èyí kọọkan ní olùdarí rẹ̀, àti àwọn ìpín mókànlélógún (21), èyí kọọkan ní olùkànsí ẹ̀ka rẹ̀. Àwọn ẹ̀ka, pẹ̀lú àwọn ìpín tí wọ́n ní, ni:
|url-status=
ignored (help)