Muhammad Sahool Bhagalpuri (tí ó papòdà ní ọdún 1948) jẹ́ ọmọ India, onímọ̀ ẹ̀sìn Islam àti oní Juri tí ó jẹ́ Mufti àgbà karun-un ti Darul Uloom Deoband.
Muhammad Sahool Bhagalpuri ni wọ́n bí ní Puraini, Bhagalpur, sí inú ẹbí Mùsùlùmi ìran Uthman.
Sahool kọ́ ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ nínú ilé ó sì tún kọ́ Ashraf Alam. ó tẹ̀síwájú sí Madrasa Jām'i al-Ulūm Kanpur ní bi tí o ti kọ́ẹ̀kọ́ pẹlu Ashraf Ali Thanwi ati Muhammad Ishāq Burdwāni. Ó tún tẹ̀síwạjú pẹlu Muhammad Farooq Chiryakoti ní Madrasa Faiz-e-Aam. Ó tẹ̀síwájú sí Hyderabad tí o ti kọ́ nípa Logic, philosophy, astronomy, literature àti fiqh pẹlu Lutfullah Aligarhi ati Abd al-Wahhāb Bihāri. Ó tẹ̀síwájú lọ sí Delhi lati gba ẹ̀kọ́ Nazīr Hussain, kí ó to darapọ̀ mọ́ Darul Uloom Deoband ní bi tí o ti kọ́ ahadith pẹlu Mahmud Hasan Deobandi ti ó sì kẹkọ parí níbè.
Wọ́n yan Sahool gẹ́gẹ́bí olùkọ́ ní Darul Uloom Deoband lẹ́yiǹ ìkẹ́kọ gboye. Ó ṣisẹ́ olùkọ́ ní ile ìwé naa fún bí ọdún mẹ́jọọ. O tún ṣiṣẹ́ pẹlu Madrasa Azizia, Calcutta Alia Madrasah àtiSylhet Government Alia Madrasah gẹ́gẹ́bí olùkọ́ agba àti adarí olùkọ́ fún hadith ní ọdún 1920. wọ́n tún fún ni ipò adarí olùkọ́ ni Madrasa Alia Shamsul Huda ni Patna lati gba ipò lọ́wọ́ Muhammad Shafi Usmani, oun ni Mufti àgbà karun-un fun Darul Uloom Deoband láti ọdún 1355 AH títídé ọdún1357 AH ó se àgbékalẹ̀ a--fihàn 15, 185 fatawa ní akoko ìdarí rẹ̀.
Sahool papòda ní ọdún 1948 (27 Rajab 1367 AH) wọ́n sin-in ni Pureni.
Dār al-Suhūl, ní Ariwa Naazimabad ṣe àtẹ̀jáde ìwé àgbékalẹ̀ ẹ̀sin Mahmūd al-Fatāwa, tí wọ́n tún mọ̀ si Fatāwa Suhūliya. Àkọ́kọ fatawa ni wọ́n fún Muhibbullah, tí ó jẹ́ olùkọ́ Jamia Uloom-ul-Islamia látọwọ́ Muhammad Saadullah Usmani ọmọ-ọmọ Sahool. Muhibullah siṣẹ lelórí, ó ko jọ pọ o sì se àtẹ̀jade rẹ.
Ìtọ́kasí
Rizwi, Syed Mehboob. Tarikh Darul Uloom Deoband [History of the Dar al-Ulum Deoband]. Vol. 2. Translated by Murtaz Husain F Quraishi (1980 ed.). p. 190.
Rafīq Ahmad Balākoti (July–August 2016). "Hadhrat Mufti Muhammad Sahool Usmani - A Biographical Sketch". Darul Uloom (in Urdu). Darul Uloom Deoband. 100 (7–8). Retrieved 7 September 2020.
Rizwi, Syed Mehboob. Tarikh Darul Uloom Deoband [History of the Dar al-Ulum Deoband]. Vol. 2. Translated by Murtaz Husain F Quraishi (1980 ed.). p. 191.
Asir Adrawi. Tazkirah Mashāhīr-e-Hind: Karwān-e-Rafta (in Urdu) (2nd, April 2016 ed.). Deoband: Darul Muallifeen. p. 115.
Editorial (March 2017). "A Review of Mahmūd al-Fatāwa". Bayyināt (in Urdu). Jamia Uloom-ul-Islamia: 59. Retrieved 7 September 2020.
Bibliography
Rizwi, Syed Mehboob. "Maulana Mufti Muhammad Sahool". Tarikh Darul Uloom Deoband [History of the Dar al-Ulum Deoband]. Vol. 2. Translated by Murtaz Husain F Quraishi (1981 ed.). Deoband: Darul Uloom Deoband. pp. 190–191.