Mawlānā Nizāmuddīn Asīr Adrawi | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 1926 Adari, United Provinces, British India (today Mau district, Uttar Pradesh, India) |
Aláìsí | 20 May 2021 Adari, Uttar Pradesh, India | (ọmọ ọdún 94–95)
Iléẹ̀kọ́ gíga | |
Notable work | Tarikh Jamiat Ulema-e-Hind|Tehreek-e-Azadi aur Musalman| Karwan-e-Rafta |
Movement | Deobandi |
Nizāmuddīn Asīr Adrawi (tí a sì mọ̀ sí Asīr Adrawi; láti ọdún 1926 títí dé ọjọ́ ogún oṣù karùn-ún ọdún 2021) jẹ́ onímọ̀ ìjìnlè mùsùlùmí ti ilẹ̀ India, ò sí tún jẹ́ òǹkọ̀wé ìtàn nípa ìgbésí ayé ẹni àti òǹkọ̀wé nínú èdè Urdu. Ó ṣe ìdásílẹ̀ Madrassa Darus Salam ni ìlú Adari, ó sì tún jẹ́ adarí Jamiat Ulama-e-Hind ní Lucknow láti ọdún 1974 títí dé ọdún 1978.
Nizāmuddīn Asīr Adrawi (tí a sì mọ̀ sí Asīr Adrawi; láti ọdún 1926 títí dé ọjọ́ ogún oṣù karùn-ún ọdún 2020) jẹ́ onímọ̀ ìjìnlè mùsùlùmí ti ilẹ̀ India, ò sí tún jẹ́ òǹkọ̀wé ìtàn nípa ìgbésí ayé ẹni àti òǹkọ̀wé nínú èdè Urdu. Ó ṣe ìdásílẹ̀ Madrassa Darus Salam ni Adari tí ó ti jẹ́ adarí ipò Jamiat Ulama-e-Hind ní Lucknow láti ọdún 1974 títí dé ọdún 1978.
Asir fìgbà kan jẹ́ olóòtú Tarjuman olóṣoosù mẹ́ta, ó sì kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé fún un. Òun tún ni òǹkọ̀wé Al-Jamiat ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ àti Al-Jamiat ti Jamiat Ulama-e-Hind olójoojúmọ́. Ó kọ àwọn ìtàn kéékèèké àti àwọn ìtàn akọni bíi Itna, Do LāsheiN, Nashīb-o-Farāz and Aetirāf-e-Shikast.
Asir kú ní ọjọ́ ogún, oṣù karùn-ún, ọdún 2021 ní Adari, Mau, ní Uttar Pradesh. Arshad Madani fi ìkẹ́dùn rẹ̀ hàn, ó sì ní pé "ikú Asir Adrawi jẹ́ ìpàdánù tí ò ṣe é dá padà."[1]
Asir kọ ìtàn ìgbésíayé àwọn ènìyàn bíi Muhammad Qasim Nanautawi, Mahmud Hasan Deobandi, Imamuddin Punjabi, Rahmatullah Kairanawi, Rashid Ahmad Gangohi àti Hussain Ahmed Madani. Ó ṣe àgékùrú apá mẹ́rẹ̀rin Tarikh-e-Islam tí Muinuddin Ahmad Nadwi kọ sí apá márùn-ún tó kéré. Ìwé rẹ̀ Tahrik-i-azadi aur Musalman, wà lára àwọn àkóónú iṣẹ́ fún Darul Uloom Deoband àti àwọn ilé-ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Islam lóríṣiríṣi.
A
Afkār-e-Aalam