Nnorom Azuonye tí a bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù keje ni ìpínlè Abia ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ òǹkọ̀wé, adarí eré orí ìtàgé, òǹkọ̀tàn àti akéwì. Ó tún jẹ́ oníwàásù ní ìjọ Methodist ní ìlú Britain. Àwọn ìwé tí ó ti kọ ni Letter to God & Other poems ní ọdún 2003, The Bridge Selection: Poems for the road ní ọdún 2005 & 2012 àti Funeral of the Minstrel ní ọdún 2015. Òun ni olùdarí àti alágbàátẹrù SPM Publications Ltd. Òun náà ni olùdásílẹ̀ àti alábòójútó Sentinel Poetry Movement tí ó sì tún jẹ́ olùdásílẹ̀ àti òǹtẹ̀wé magasíìnì Nollywood Focus, Sentinel Literary Quarterly, Sentinel Nigeria àti Sentinel Champions.[1][2]