Níji Àkànní

Níji Àkànní jẹ́ ọmọ orilẹ-èdè Nàìjíríà, òṣeré ìtàgé, olùdarí, alákòóso àti olùgbé fíìmù jáde ni[1].

Ìtàn Ilé Ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àkànní gba ìwé ẹ̀rí àkọ́kọ́ ti yunifásítì nínú ìmò ìjìnlẹ̀ Ère ìtàgé láti ilé ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ ni Ilé-Ifẹ̀ àti ìwé ẹri kejì ti yunifásítì nínú ìmò ìjìnlẹ̀ fíìmù ṣíṣe láti Yunifásítì tí Ìbàdàn bákan náà ni ó gbà ìwé ẹ̀rí akọ́ṣẹ́-mọṣẹ́ lórí bí a ṣe ń gbé ète fíìmù ka'lẹ́ àti bí a ti ń darí fíìmù láti ilé iṣẹ́ tó ń ṣe àmójútó fíìmù àti ẹ̀ka móhùnmáwòran ni orílẹ̀-èdè India[2].

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù ni o dá ète rẹ kọ, nígbàtí o fi ọwọ́sowọpọ pèlú àwọn ẹlòmíràn láti dà ète àwọn fíìmú míràn kọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Gẹ́gẹ́bi ọ̀kan lára àwọn aṣojú mẹ́ta láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà níbi ìpàtẹ Àṣà Olympiad ní ìlú London ní ọdún 2012, òun ní olùdarí fún The Lion and the Jewel, eré oníṣé ti Ọ̀jọ̀gbọ́n Wọlé Sóyinká kọ èyi ́tí a sọ di eré orí ìtàgé fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọdún 1959. Ní ọdún 2005, oun ni igbákejì olùdarí fún sáà àkọ́kọ́ eto kan ti a pe ni Amstel Malta Box Office, tii ṣe eto ori mohunmaworan ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó n fi igbe aye àwọn ènìyàn hàn.

Ní ọdún 2006, oun ni olùdarí ète fún ètò kan ti a pe ní Big Brother Nigeria, tíí ṣe ètò ori móhùnmáwòran tó n fi ìgbẹ́ ayé àwọn ènìyàn hàn gbangba, ni ọdún yíì bakanna, o fi ọwọ́sowọ́pọ̀ pèlú olùdárí míràn láti darí fíìmú ti a mò sí The Narrow Path (Ònà tooro)[3], tii ṣe fíìmú oní ìṣẹ́jú márùn-dín-lọ́gọ̀rún ti a ti ọwọ́ ilé iṣẹ́ Òpòmúléró (Mainframe Films àti Telifísàn Productions) gbẹ́ jádẹ, Túndé Kèlání lo darí fíìmú naa. Fíìmú yíì, ti òṣèré bíi Ṣọlá Àsedèko àti Khàbíràt Káfidípé kó'pa nínú rẹ ni ìtàn inú rẹ dá lórí ìwé tí a n pé àkọlé rẹ ní The Virgin, (Wúndíá w) tíí ṣe ìwé àkókó ti a ti ọwọ́ Báyò Adébọ̀wálẹ́ kọ. Ní ọdún 2008, ó tún darí Abọ́bakú,[4] tii se fíìmú o ni kúkúrú ti Fẹ́mi Odùgbẹ̀mí gbẹ́ jádẹ lórí ètò móhùnmáwòran MNET kan ti wọn pe ní iṣẹ́ kanṣe New Directions. ''Abọ́bakú'' gbà àmì ẹ̀yẹ fún fíìmú kúkúrú ti o dára jùlọ ní àjọ̀dún fíìmú ti ZÚMÀ ní ìlú Àbújá, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún 2010, òun kanna ni a tún fún ní àmì ẹ̀yẹ fún fíìmú kúkúrú ti o dára jùlọ ní àmì ẹ̀yẹ TERRACOTA Awards nì ìlú Èkó, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ní ọdún 2010, Àkànní kọ eré Aramọ́tu o si tún darí rẹ, Aramotu jẹ eré oníṣé láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà,Gabriel Afoláyan lo kó'pa nínú fíìmú náà. A dárúkọ fíìmú yíì fún àmì ẹ̀yẹ mẹ́jẹ níbi Ayẹyẹ fíìmù ilẹ̀ adúláwọ̀ ẹlẹ́ẹ̀keje   ó sì gbà àmì ẹ̀yẹ fíìmù orílè-èdè Nàìjíríà tí ó dára jù lọ àti àmì ẹ̀yẹ fún fíìmù tí aṣọ wíwọ̀ rẹ̀ dára jù lọ. Fíìmù yìí kan náà ni ó gbà àmì ẹ̀yẹ fún fíìmù tí ó dára jù lọ ní Àjọ̀dún Fíìmù lágbàyé fún Ilẹ̀ Aláwọ̀ Dúdú tí ó wáyé ní ìlú Càlàbar ní oṣù karùn-ún ọdún 2013. A ti ṣe àfihàn Aramótù ni onírúurú àjọ̀dún fíìmù káàkiri àgbáyé, lára èyí tí àjọ̀dún Samsung Women's International Film Festival (SWIFF) ni ọdún 2012 ní ìlú Chennai, orílẹ̀-èdè India jẹ́; ní ọdún 2012 yìí kan náà àjọ̀dún fíìmù Africa In The Picture (AITP), ní ìlú Amsterdam ṣe àfihàn Aramótù; ní ọdún 2013, àjọ̀dún fíìmù Àrùshà Áfríkà International Film Festival (AIFF), ní orílè-èdè Tanzania; àti àjọ̀dún International Fíìmú Festival of Kerala (IFFK), ní orílè-èdè India náà ṣe àfihàn fíìmù yìí.

Òun ni ó dárí tí ó sì tún ṣètò ète fún fíìmù Heroes and Zeros, tíì ṣe fíìmù orilẹ-èdè Nàìjíríà tí àwọn òṣeré bíi Nadia Buari, Bimbo Manuel, Gabriel Afoláyan, Linda Ejiofor àti Olu Jacob's kó'pa nínú ẹ̀[5]. A gbé fíìmù yìí jáde ní ọjọ́ keje oṣù kẹsàn-án ọdún 2012, o sì fara hàn ní ilé sinimá ní ìlú ọba (the UK) ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kẹta ọdún ní 2013 ni ilé sinimá Odeon. Fíìmù yìí gbà àmì ẹ̀yẹ fíìmù tó ta yọ julọ àti ti fíìmù tí àwọn ènìyàn wò julọ níbi ayẹyẹ àmì ẹ̀yẹ ÈKÓ International Fíìmú Festival ni ọdún 2013 ó sì figagbága pèlú àwọn fíìmù míràn níbi ẹ̀ka fíìmù díjítà ní ọdún 2013 nínú àjọ̀dún Pan Áfríkà Fíìmú àti Television Festival, FESPACO, ní ìlú Ouagadougou, ní orílè-èdè Burkina Faso. Ní ọdún 2013, fíìmù yìí farahàn ni International Fíìmú Festival ti Kerala, IFFK, ní orílè-èdè India, a sì tún ṣe àfihàn rẹ ni ọdún 2014 níbi ayẹyẹ àjọ̀dún Afrikamera Fíìmú Festival ìlú Warsaw, ní orílè-èdè Poland. A dárúkọ fíìmù yìí fún àmì ẹ̀yẹ mẹ́fà níbi Africa Movie Academy Awards ẹlẹ́ẹ̀kẹsàn o sì gba àmì ẹ̀yẹ fún fíìmù tí àtúntò rẹ dára jù lọ, tí ète àgbékalẹ̀ dúró déédéé àti èyí tí ìdarí rẹ múná dóko.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Hjort, M. (2013). The Education of the Filmmaker in Africa, the Middle East, and the Americas. Global Cinema. Palgrave Macmillan US. p. 67. ISBN 978-1-137-03269-0. https://books.google.co.uk/books?id=fVSYAAAAQBAJ&pg=PT67. Retrieved 2019-11-21. 
  2. Ekenyerengozi, M.C. (2013) (in ta). NOLLYWOOD MIRROR®. Michael Chima Ekenyerengozi. p. 21. ISBN 978-1-304-72953-8. https://books.google.co.uk/books?id=RL01BgAAQBAJ&pg=PA21. Retrieved 2019-11-21. 
  3. Kerr, D.; Banham, M.; Gibbs, J.; Plastow, J.; Osofisan, F. (2011). African Theatre: Media & performance. African theatre. James Currey. p. 38. ISBN 978-1-84701-038-4. https://books.google.co.uk/books?id=dFzMC-nHqi4C&pg=PA38. Retrieved 2019-11-21. 
  4. "Films". Africultures (in Èdè Faransé). 2010-07-17. Retrieved 2019-11-21. 
  5. Adeyemo, Adeola; Adeyemo, Adeola; Adeyemo, Adeola (2012-08-20). "Nadia Buari, Olu Jacobs, Gabriel Afolayan & Bimbo Manuel Star in Heroes & Zeros – View Behind the Scenes Shots and Trailer". BellaNaija. Retrieved 2019-11-21.