Oladipo Diya

Oladipo Diya
9th Chief of General Staff
In office
1993–1997
ÀàrẹGen. Sani Abacha gegebi Olori Orile-ede
AsíwájúAdm. Augustus Aikhomu
Arọ́pòAdm. Mike Akhigbe
Chief of Defence Staff
In office
1993–1993
AsíwájúGen. Sani Abacha
Arọ́pòGen. Abdulsalami Abubakar
Governor of Ogun State
In office
January 1984 – August 1985
AsíwájúOlabisi Onabanjo
Arọ́pòOladayo Popoola
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí3 Oṣù Kẹrin 1944 (1944-04-03) (ọmọ ọdún 80)
Odogbolu, Ogun State, Nigeria
Alma materNigerian Defence Academy
Military service
Allegiance Nigeria
Branch/serviceNigerian Army
Years of service1964-1997
RankLieutenant General

Donaldson Oladipo Diya (tí a bí ní ọjọ́ kẹta oṣu kẹrin, odún 1994 - 26 Oṣù Kẹta 2023) jẹ́ ajagun gbogboogbò ti orílẹ̀-èdè Naijiria tí ó sì ti fìgbà kan jẹ́ oloyè àwọn ajagun ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó sì tún jẹ́ igba-keji aare ti Nàìjíríà lábẹ́ ìjọba ológun ti olórí ìlú Sani Abacha láti ọdún 1994 títí tí wọ́n fi fi ẹ̀sùn ọ̀tẹ̀ kàn án ní ọdún 1997.[1] Ó fìgbà kan jẹ́ oloye akogun àti gómìnà ológun ti Ogun State láti oṣu kìíní, ọdún 1984 títí di oṣu kẹjọ ọdún 1985.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọjọ́ keta, oṣu kerin, ọdún 1944 ni a bí Donaldson Oladipo Diya sí ìlú Odogbolu, Ipinle Ogun, tó filgbà kan jẹ́ ti apa iwo-oorun, ile Nàìjíríà Ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Methodist ní Ipinle Eko ni ó ti kàwẹ́.

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ológun

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Diya dara pọ̀ mọ́ Nigerian Defence Academy, ti Ipinle Kaduna [2] ó sì ja Ogun Abẹ́lé Nàìjíríà Lẹ́yìn náà, ó lọ sí US Army School of Infantry, ti Command and Staff College, Jaji (láti ọdún 1980 títí wọ ọdún 1981) ní National Institute for Policy and Strategic Studies, Kuru. Nígbà tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìjọba ológun lọ́dún náà lọ́hùn-ún, ó lọ sí Ahmadu Bello University, ti ìpínlẹ̀ Zaria, láti lọ gboyè nínú ẹ̀kọ́ Law, ibẹ̀ sì ni ó ti gboyè LLB. Lẹ́yìn náà, ní Nigerian Law School, wọ́n pè é wọ bar láti wá dara pọ̀ mọ́ àwọn amòfin ti ilẹ̀ Nàìjíríà ni Ilé-ẹjọ́ Gígajùlọ ilẹ̀ Nàìjíríà.[1]

Oladipo Diya ni adarí àwọn ajagun ìkọkànlélọ́gbọ̀n. Wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí gómìnà ológun ti Ipinle Ogun ní oṣù kìíní ọdún 1984 títí wọ oṣu kẹjọ, ọdún 1985.

Olóyè àwọn oṣìẹ́ àpapọ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí olóyè àwọn òṣìṣẹ́ àpapọ̀ ní ọdún 1993 àti igbá kejì alága ti Provisional Ruling Council ní ọdún1994.[1] Gẹ́gẹ́ bí Chief of the Defence Staff (Nigeria) ó sì jẹ́ igbá kejì ààrẹ de facto ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà ìjọba ológun ti Sani Abacha láti ọdún 1994 títí wọ́n fi fi ẹ̀sùn ọ̀tẹ̀ kàn án ní ọdún 1997.[1] Alákòóso àwọn òṣìṣẹ́ nígbà náà ni Bode George[3]

Ìgbìmọ̀ ọ̀tẹ̀ ti ọdún 1997

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 1997, Diya àti àwọn sójà kan gbìmọ̀ pọ̀ láti ṣí Sani Abacha nídìí kúrò lórí oyè kí wọ́n ba lè joyè ọ̀hún. Àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ tó ṣe olóòótó sí Abacha ló lọ túfọ̀ fun. Èyí sì mu kí wọ́n gbé Diya àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣẹ̀wọ̀n. Wọ́n fi ẹ̀sùn òtẹ̀ kàn wọ́n, wọ́n sì gbé wọn lolé ẹjọ́ tí wọ́n wá padà dájọ́ ikú fún wọn. Ní odún 1998, Abacha fòṣánlẹ̀, ó kú, Abdulsalami Abubakar[4] sì di olórí ìlú lẹ́yìn rẹ̀. Olórí ìlú yìí ló pàṣẹ pé kí wọ́n tú Diya sílẹ̀.

Ọ̀pọ̀ èèyàn gbàgbọ́ pé Abacha lọ́wọ́ sí ìgbìmọ̀ ọ̀tẹ̀ tí Diya ṣe, ìdí abájọ ni pé kí ó ba lè ṣe Diya mọ̀ṣẹ́ nítorí Diya ti ń di gbajúgbajà láàrin ìlú. Kí ó tó dìgbà yìí, àwọn òṣìṣẹ́ tó jẹ́ olóòótọ́ sí Abacha ti gbìyànjú láti pa Diya rí lẹ́ẹ̀mejì àmọ́ wọn ò ri pa. Àwọn tó yànnàná ìṣẹ̀lẹ̀ náà sọ ọ́ di mímọ̀ pè ìṣẹ̀lẹ̀ òhún fi hàn gbangba-gbàǹgbà pé ìpínyà ti wà láàrin àwọn aṣèjọba ológun, àti pé èrò Abacha ni láti wà lórí oyè náà kí ó le bà di ààrẹ orílẹ̀-èdè Naijiria.[5]

Olóògbé olóyè Gani Fawehinmi, tí ó fìgbà kan jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn fi lé lẹ̀ nínú ìweh-ìròyìn Post Expressgbogbo àwọn èèyàn tí wọ́n dárúkọ pé ó wà nínú ìgbìmọ̀ ọ̀tẹ̀ náà jẹ̀ àwọn ọmọ Abacha, tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ si, nítorí ìdí èyí, ọ̀rò náà dojúrú, ó sì ta kòkò.[6]

Ẹjọ́ ikú rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Léyìn tí wọ́n tì í mọ́lé, wọ́n dájọ́ ikú fún Diya àti èèyàn márùn-ún mìíràn ní oṣù kẹrin, ọdún 1998. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí wọ́n ṣe, Diya fi ìdí ẹ̀ múlẹ̀ pè ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ̀ tó súnmọ́ Abacha pẹ́kípẹ́kí, Gen. Ishaya Bamaiyi, ni ó fi ọ̀rọ̀ náà lọ òun, tí ó sì ní kí wọ́n gbìmọ̀ ọ̀tẹ̀ fún Abacha . Àwọn ìjọba sì fi ọ̀rọ̀ náà pamọ̀ fún àwọn ará-ìlú.

Olórí àwọn agbófinró ológun ìgbà náà ni General Victor Malu, tí ó fìgbàn kan jẹ́ adarí àwọn ọ̀wọ́ tó ń rí sí ìfọ̀rọ̀ àlàáfíà lélẹ̀ ti West African region ECOMOG, fi ìdáhùn sì ẹjọ́ Diya, ó sì sọ pé ìjẹ́wọ́ Diya ò ṣe pàtàkì àti pé ohun tí òun fẹ́ kí Diya ṣe ni láti fi hàn pé kò sí lára àwọn ìgbìmọ̀ ọlọ́tẹ̀ ọ̀hún.[7]

Ìjọba ilẹ̀ South Africa bi wọ́n lẹ́jọ́ lahtàri àṣírí tí wọ́n ń fi bò, ó sì kì wọ́n nílọ̀ láti mà ṣe ìdájọ́ ikú fún Diya àti àwọn èèyàn rẹ̀ bí wọn ò bá lẹ́rìí tó dánjú, nítorí èyí lè bí wàhálà láàrin àwọn ará-ìlú náà àti lókè òkun. Abdulsalami Abubakar, tó gorí oyè lẹ́yìn Abacha padà figi lé ẹjọ́ ikú tí wọ́n dá fún Diya.[8]

Wọ́n padà tú Diya sílẹ̀, wọ́n sì gba agbára àti àṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀, wọ́n gba ipò lọ́wọ́ rẹ̀ pẹ̀lú, wọ́n sì ní kò gbọdọ̀ lo orúkọ oyè rẹ̀ mọ́.

Iṣẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lẹ́yìn tí wọ́n tu sílẹ̀, Diya kọ̀ láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Oputa Panel nígbà tí Oputa ń fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò lórí iṣẹ́ rẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ igbá kejì ààrẹ. Ó fi gbogbo àkókò rẹ̀ tiraka láti mú àwọn ohun ìní rẹ̀ padà bọ̀ sípò lẹ́yìn tí ìjọba ti gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ohun ìní rẹ̀. Ìdí abájọ ni pé kò ṣàlàyé bí ó ṣe rówó láti ra àwọn nǹkan iyebíye tó ní níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé owó oṣù rẹ̀ ò tó nǹkan kan.[8]

Ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù karùn-ún, ọdún 2020, ìyàwó kejì Diya di olóògbé.[9] Ìròyìn fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àrùn COVID-19 ló pa á, àti pé ìyàwó rẹ̀ àkọ́kọ́ náà ti kó àrùn náà.[10]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 "Lt. General Oladipo Diya Chief of General Staff (1993–1997)". Federal Ministry of Information and Communications. Archived from the original on 2012-03-02. Retrieved 2010-01-04.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. Nigeria, Media (2018-06-06). "Biography Of Oyewole Diya". Media Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-06-19. Retrieved 2020-05-29. 
  3. Jide Ajani (October 27, 2009). "Night of long knife for Bode George...a news analysis". Vanguard News. Archived from the original on January 11, 2018. Retrieved 2009-11-09.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "Abacha's henchman al-Mustapha sings briefly about "Abubakar-Diya Coup" plot, the killing of Abiola, NADECO and other issues". USAfricaonline. Archived from the original on 2009-09-24. Retrieved 2010-01-04. 
  5. French, Howard W. (1997-12-24). "The Enemy Within" (in en-US). The New York Times. ISSN 0362-4331. https://www.nytimes.com/1997/12/24/world/the-enemy-within.html. 
  6. April 3rd, admin on; 2020. (2020-04-03). "Oladipo Diya Celebrates His 76th Birthday Today". Kesere Muzic. Archived from the original on 2020-06-19. Retrieved 2020-05-29. 
  7. "ABACHA'S FORMER DEPUTY, OLADIPO DIYA TURNS 76 TODAY – Abuja Reporters". abujareporters.com.ng. Retrieved 2020-05-29. 
  8. 8.0 8.1 Press, Associated. "Nigeria Arrests General Accused in a Coup Plot". NY Times. Retrieved 27 January 2019. 
  9. "Nigeria's Ex-Chief Of General Staff, Oladipo Diya, Loses Wife". Sahara Reporters. 2020-05-20. Retrieved 2020-07-13. 
  10. "Diya's younger wife, Shade, dies of COVID-19 as second wife down with virus". Businessday NG (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-05-20. Retrieved 2020-07-13.