Olawale Adeniji Ige | |
---|---|
Minister of the Federal Ministry of Aviation | |
In office 1993–1994 | |
Minister of the Federal Ministry of Communications | |
In office 1990–1992 | |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Lagos, Nigeria | 13 Oṣù Kẹ̀wá 1938
Aláìsí | 9 May 2022 | (ọmọ ọdún 83)
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | Non-Partisan |
Olawale Adeniji Ige MFR (13 October 1938 – 9 May 2022)[1] fìgbà kan jẹ́ onímọ̀-ẹ̀rọ àti mínísítà tó ń rí sí ètò ìbánisọ̀rọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, láti ọdún 1990 wọ 1992.[2] Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i mínísítà tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ọkọ̀ òfuurufú(1993).[3]
Wọ́n bí i ní 13 October, ọdún 1938 ní Ògbómọ̀ṣọ́, èyí tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ní orílẹ̀-èdè Naijiria. Ó kàwé ní Baptist Boys High School, ní Abẹ́òkúta, tó jẹ́ olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Ògùn, ní Nàìjíríà, láti ọdún 1951 wọ 1956. Ibí sì ni ó ti gba ìwé-ẹ̀rí West African School Certificate (WASC). Ó tẹ̀síwájú láti lọ Polytechnic, Regent Street, London tó ti di University of Westminster, níbi tí ó ti gba oyè Diploma nínú ìmọ̀ electrical engineering.[4] Ó padà di akẹ́kọ̀ọ́ gboyè láti Institute of Electrical and Electronics Engineers ní ọdún 1965.[5]
Ó padà sí Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ onímọ̀-ẹ̀rọ ní ọdún 1967, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Federal Ministry of Communications níbi tí ó ti di olùdarí àgbà ní ọdún 1989.[6][7] Wọ́n yàn án sí ipò mínísítà tó ń rí sí ètò ìbánisọ̀rọ̀ ní ọdún 1990, títí wọ ọdún 1992. Wọ́n sì tún yàn án gẹ́gẹ́ bí i mínísítà tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ọkọ̀ òfuurufú, ni họdún 1993.[8] Òun ni alága àkọ́kọ́ ti Nigerian Telecommunications Limited, NITEL, tí kì í ṣe ológun. Bákan náà, òun ni alága ìgbìmọ̀ Nigerian Internet Group,[9] ó sì tún wà lára àwọn ìgbìmọ̀ Nigerian Communications Commission, NCC.[10]