Omo Ghetto | |
---|---|
Adarí | Abiodun Olanrewaju |
Olùgbékalẹ̀ | Funke Akindele |
Òǹkọ̀wé | Funke Akindele |
Àwọn òṣèré | Funke Akindele Eniola Badmus Bimbo Thomas Ireti Osayemi Esther Kalejaiye Adebayo Salami Taiwo Ibikunle |
Orin | Baba Nee |
Ilé-iṣẹ́ fíìmù | Scene One Productions |
Olùpín | Olasco Films Nig. Ltd. |
Déètì àgbéjáde | 24 October 2010 |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Èdè | Yoruba |
Omo Ghetto jẹ́ fíìmù àgbéléwò apanilẹ́rìn-ín ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tó jáde ní ọdún 2010. Olùarí fíìmù náà ni Abiodun Olarenwaju, àwọn òṣèré tó sì kópa nínú fíìmù náà ni Funke Akindele, Bimbo Thomas, Ireti Osayemi, Esther Kalejaiye àti Eniola Badmus[1].
FÍìmù náà dá lórí àwọn ìwà búburú lóríṣiríṣi tó wà nínú àwùjọ, èyí tó níṣe pẹ̀lú àwọn obìnrin tó ń ṣe jàgídíjàgan káàkiri. Ó ṣe àfihàn ẹbí, ìrúfin àti ìfọwọ́sowọpọ̀ àwọn arábìnrin.
Olusegun Michael for Modern Ghana gbé -ìtàn, àwọn òṣèré, àkọ́lé àti ìṣètumọ̀ àwọn ojúṣe nínú fíìmù náà, ó sì pè é ní fíìmù tó kún fún ìdánilárayá àti iṣàfihàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan[2]. Ní ọdún 2017, Azeezat Kareem fún Encomium Magazine ṣe àtòpọ̀ fíìmù Omo Ghetto gẹ́gẹ́ bí i ọ̀kan lára àwọn fíìmù méjì tó gbé Eniola Badmus wá sí ìta gbagede tó fi di gbajúmọ̀ òṣèré[3]. Legit.ng náà tún tò ó pọ̀ mọ́ ọ̀kan lára àwọn fíìmù márùn-ún tí a kò le gbàgbé, tó jẹ́ fíìmù Funke Akindele[4].
Àfihàn àkọ́kọ́ fún fíìmù náà wáyé ní Exhibition Hall, ní National Arts Theatre, Iganmu ní oṣùOctober, ọjọ́ 24, Ọdún 2010[5].
Omo Ghetto: The Saga ni apá kejì fíìmù yìí, ó sì jáde ní ọjọ́ 25 oṣù December, ọdún 2020[6][7].