Osmania Medical College | |
---|---|
Osmania Medical College.jpg | |
Motto | Sincerity Service Sacrifice |
Established | 1846 |
Type | Public |
Religious affiliation | Kaloji Narayana Rao University of Health Sciences |
Principal | Dr. Narendra Kumar Are |
Students | 250 students per academic year |
Location | Hyderabad, Telangana, India |
Website | osmaniamedicalcollege.org |
Osmania Medical College, tó fìgbà kan jẹ́ Hyderabad Medical School, jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ elétò ìlera ní Hyderabad, Telangana, India. Wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ rẹ̀ ní ọdún 1846, láti ọwọ́ Nizam ẹlẹ́ẹ̀karùn-ún ti Hyderabad àti Berar, Afzal ud Dowla, Asaf Jah V. Ilé-ẹ̀kọ́ náà wà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ètò Osmania University tẹ́lẹ̀, àmọ́ ó wà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kaloji Narayana Rao University of Health Sciences báyìí, àti Osmania General Hospital.[1][2] Lẹ́yìn ìdásílẹ̀ Osmania University ní ọdún 1919, wọ́n yí orúkọ ilé-ẹ̀kọ́ náà sí Osmania Medical College, lẹ́yìn Nizam of Hyderabad ẹlẹ́ẹ̀keje, Mir Osman Ali Khan.[3] Ipò ẹlẹ́ẹ̀kejìdínláàádọ́ta ní ilé-ẹ̀kọ́ náà wà ní National NIRF Medical University Rankings 2024.[4]