Pamela Nomvete (bíi ni ọdún 1963) jẹ́ òṣèré ni orílẹ̀ èdè South Áfríkà. Wọ́n bí Pamela sì orílẹ̀ èdè Ethiopia, ṣùgbọ́n àwọn òbí rẹ jẹ ọmọ orílẹ̀ èdè South Áfríkà. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Royal Welsh College of Music and Drama[1] [2]. Ní ọdún 1990, Nomvete bẹ̀rẹ̀ eré orí tẹlẹfísọ̀nù, ó sì di gbajúmọ̀ nípa eré Generations.[3] Ó kọ ipá Ntsiki Lukhele nínú eré náà. Lẹ́yìn tí òun àti ọkọ rẹ̀ pínyà, ìrònú dé ba, ó sì ní oríṣiríṣi ìṣòro, ó ní ìgbà kan tí ó ń gbé nínú ọ̀kọ̀ rẹ̀, tí ó wà ń ta aṣọ rẹ̀ fún oúnjẹ àti sìgá. Ní ọdún 2004, ó kó ipa Thandi nínú eré Zulu Love letter.[4] Ní ọdún 2012, ó kópa gẹ́gẹ́ bí Mandy Kamara nínú eré Coronation Street.[5] Ní ọdún 2013, ó kọ ìwé ìtàn nípa ayé rẹ, o si pe àkọlé rẹ̀ ni Dancing to the Beat of the Drum: In search of my spiritual home.[6]