Paschaline Alex Okoli | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Nigeria |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Imo State University |
Iṣẹ́ | Actress |
Ìgbà iṣẹ́ | 2010–present |
Paschaline Alex Okoli jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ Cordelia nínu eré aláwàdà kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Jenifa's Diary .
Paschaline wá láti agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Orumba south local government ní Ìpínlẹ̀ Anámbra. Ó gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ èdè Faransé láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì Ìpínlẹ̀ Ímò.[1]
Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ ní ọdún 2010 pẹ̀lú kíkópa nínu fíìmù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Definition Of Love.[2] Ṣùgbọ́n ó di ìlúmọ̀ọ́ká nígbà tí ó kópa gẹ́gẹ́ bi Cordelia nínu eré aláwàdà kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Jenifa's Diary,[3][4] èyí tí ó ṣe pẹ̀lú Fúnkẹ́ Akíndélé.
Wọ́n yaan Paschaline fún àmì-ẹ̀yẹ City People Movie Award kan ní ẹ̀ka ti ojú tuntun òṣèré tí ó dára jùlọ nínu ọdún (eré èdè Gẹ̀ẹ́sì).
Paschaline ti sọ nígbà kan rí pé òun le kó ipa oníhòhò tí wọ́n bá le san owó tí ó tówó fún òun.[5][6][7][8] Paschaline maá n gbé àwọn fọ́tò ara rẹ̀ tí kò fẹ́ẹ̀ bójúmu sí orí ayélujára ní gbogbo ìgbà.[9][10]