Peju Alatise | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Àdàkọ:Bya Lagos, Nigeria |
Iṣẹ́ | Multimedia artist |
Awards | 2017 FNB Art Prize |
Peju Alatise jẹ ayàwòrán ilẹ̀ Nàìjíríà, akẹ́wì, òǹkọ̀wé, àti ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ni National Museum of African Art, tí ó jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀yà Smithsonian Institution. Ọdún 1975 ni wọ́n bí Alatise sí ìdílé mùsùlùmí òdodo ní Ìlú Èkó.[1]
Ilé-ìwé Ladoke Akintola University ní ìpínlẹ̀ Oyo, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Lẹ́yìn ìwé rẹ̀, ó ṣiṣẹ́ fún ogun ọdún ní ile-iṣẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ayàwòrán[2].
Wọn pàtẹ àwọn àwòrán iṣẹ́ rẹ̀ nínú àtúṣe tuntun ẹlékẹtàdínlọ́gọ́ta ti Venice Biennale (57th edition) tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Viva Arte Viva (Kí iṣẹ́ ọnọ̀ pé kánri-kése ).[3][4] Alatise pẹ̀lú àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjìríà méjì mìíràn Victor Ehikhamenor àti Qudus Onikeku ni wọ́n jẹ́ ọmọ Nàìjìríà àkọ́kọ́ ti yóò ni àǹfàní láti wà ni ìpàtẹ iṣẹ́-ọnọ̀ náá[5]. Àwòrán rẹ̀ dálé ìgbé ayé ọmọ ọ̀dọ̀ obìrin.[1]
Alatise gba àmì-ẹ̀yẹ FNB Art Prize ní ọdún 2017.[6]
Alatise gbé oríyìn fún ayàwòrán David Dale, Bruce Onabrakpeya, Nike Monica Davies, Susanna Wenger, Nàìjìríà àti àṣà Yoruba gẹ́gẹ́ bí ohun ìwúrí fún iṣẹ́ òun.