Reloaded (fíìmù ọdún 2009)

Reloaded
Fáìlì:Reloaded poster.jpg
Adarí
Olùgbékalẹ̀Emem Isong
Àwọn òṣèré
Orílẹ̀-èdèNigeria
ÈdèEnglish

Reloaded jẹ́ fíìmù ọdún 2009 ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó jẹ́ mọ́ eré-ìfẹ́, èyí tí Lancelot Oduwa Imasuen àti Ikechukwu Onyeka darí. Lára àwọn akópa fíìmù náà ni Ramsey Nouah, Rita Dominic, Desmond Elliot, Stephanie Okereke, Ini Edo àti Nse Ikpe-Etim.[1][2] Wọ́n yàn án fún àmì-ẹ̀yẹ mẹ́ta ní ayẹyẹ Africa Movie Academy Awards ẹlẹ́ẹ̀karùn-ún.[3]

Nollywood Reinvented fún fíìmù yìí ní ìṣèdára mẹ́ta nínú márùn-ún. Àwọn tó ṣe àríwísí sí fíìmù yìí sọ ọ́ di mímọ̀ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ti wo fíìmù náà lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà, kò ì sú àwọn.[4] NollywoodForever fún ní ìgbóríyìn 93%. Wọ́n ṣe ìgbóríyìn púpọ̀ fún fíìmù yìí nítorí àhúnpọ̀ ìtàn àti ijó tí wọ́n jó kẹ́yìn nínú rẹ̀.[5]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Nollywood starts gets Reloaded". bellanaija.com. Retrieved 15 April 2014. 
  2. "Emem and Lancelot again in Reloaded". nigeriafilms.com. Archived from the original on 11 April 2016. Retrieved 15 April 2014. 
  3. "Film Review: Reloaded". Retrieved 15 April 2014. 
  4. "Reloaded on NR". nollywoodreinvented.com. Retrieved 15 April 2014. 
  5. "Reloaded Review". nollywoodforever.com. Archived from the original on 16 April 2014. Retrieved 15 April 2014.