Reminisce (Alaga Ibile) jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ Ajilete, ìbílẹ̀ gúúsù Yewa ní ìpínlẹ̀ Ogun, apá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n bí i ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù ṣẹẹrẹ ọdún 1981, ní ìpínlẹ̀ Kaduna, apá àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
A bí Rẹ̀mílẹ́kún Khàlid Sàfárù ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù ṣẹẹrẹ, orúkọ mìíràn tí arákùnrin yìí ń jẹ́ ni orí-ìtàgé ni Reminisce àti Alága ìbílẹ̀. Ó jẹ́ olórin tàka-súfèé ti ilè Nàìjíríà, bẹ́ẹ̀ náà ni ó jẹ́ òǹkọrin àti eléré tíátà láti ìpínlẹ̀ Ògùn. Ògbóǹtarìgì ni ó jẹ́ nínú fífí èdè Gèésì àti èdè abínibí rẹ̀ Yorùbá[1][2] dánilárayá.
Reminisce (Alaga Ibile) jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ Ajilete, ìbílẹ̀ gúúsù Yewa ní ìpínlẹ̀ Ogun, apá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n bí i ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù ṣẹẹrẹ ọdún 1981, ní ìpínlẹ̀ Kaduna, apá àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Nígbà tí ó wà ní ilé ìwé, oríṣiríṣi àwọn orin tàka-súfèé tí orílè-èdè Nàìjíríà àti ti òkè-òkun ni ó máá ń gbọ́, ó sì máa ń kọ àwọn orin yìí ní orí-ìtàgé nígbàkugbà tí ilé-ìwé rẹ̀ bá ń ṣe síse. Ó mú ìdàgbàsókè bá ẹ̀bùn orin kíkọ rẹ̀ nípa gbígbọ́ orin àwọn olórin tàka-súfèé mìíràn bí i Nas, Jay z àti Snoop Dogg. Ilé- ẹ̀kọ́ gíga pólì ni ó ti ka kárà-kátà ( purchasing and supply).
Ọdún 2006 ní ó se àkójọ àwọ rẹ̀ àkọ́kọ́ ní ilé-iṣẹ́ Coded Tunes, àmọ́ àwo yìí kò jáde. Fún ìdí èyí, ó gbájúmọ́ ẹ̀kọ́ àtí píparí ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ní ọdún 2008, ó padà sí ori kíkọ. Lára àwọn orin tí ó sọ ọ́ di ìlú mọ̀ọ́ká ni: Bachelor's Life tí ó kọ pẹ̀lú 9ice, àti If Only tí Dtunez gbé jáde.
Ilé-iṣẹ́ Edge Records gbà á láti máa ṣiṣẹ́ fún wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni ó jẹ́ olùdásílẹ̀ àti olùdaeí ilé-iṣẹ́ LRR Records. Ní ọdún 2014, TIME Magazine pe REMINISCE ní (ọ̀kan nínú àwọn olórin tàka-súfèé méje tí o gbọ́dọ̀ rí) “one of the seven World Rappers You Should Meet”[3] Ọ̀kan lára àwọn ayélujára fún orin pè é ni NOTJUSTOK, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn olórin tàka-súfèé mẹ́ta tí ó mú òkè ní ọdún 2014. [4] Àwo rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "Local Rappers" tí ó gbé jáde ní ọdún 2015, èyí tí ó kọ pèlú Olamide àti Phyno mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àrínyàngiyàn dání pé àwọn tí wọ́n fi èdè Gẹ̀ẹ́sì kọrin ní ó báwí bí i MI àti Mode9.[5]