Hajia Safinatu Buhari | |
---|---|
First Lady of Nigeria | |
In role 31 December 1983 – 27 August 1985 | |
Head of State | Muhammadu Buhari |
Asíwájú | Hadiza Shagari |
Arọ́pò | Maryam Babangida |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Safinatu Yusuf 11 December 1952 Jos, Northern Region, British Nigeria (bayi Jos, Ìpínlẹ̀ Plateau, Nigeria) |
Aláìsí | 14 January 2006 | (ọmọ ọdún 53)
Ọmọorílẹ̀-èdè | Nigerian |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Muhammadu Buhari (m. 1971; div. 1988) |
Àwọn ọmọ | 5 |
Safinatu Buhari (anée Yusuf) (11 December 1952 – 14 January 2006) jẹ olùkọ Nàìjíríà atí Iyààfin Ààrẹ ilé Nàìjíríà láti 1983 sí 1985. Ó jẹ ìyàwó àkókò tí Muhammadu Buhari.
Á bí Safinatu Yusuf ní ọjọ kọkànlá oṣù Kejìlá odún 1952 sí Alhaji Yusufu Mani atí Hajia Hadizatu Mani ní ìlú Jos ní Ìpínlẹ̀ Plateau.[1] Arà ẹ̀yà Fulani tó wà ní Àríwá Nàìjíríà ní obìnrin yìí, ó sì wá láti ìjọba ìbílẹ̀ Mani ní Ìpínlẹ̀ Katsina. Ó ló sí ilé-ìwé alakọbẹrẹ Tudun Wada. Ìdílé rẹ ló sí Ìpínlẹ̀ Èkó nígbà tí komisanna fún ẹtọ Èkó nígbà náà, Musa Yar'adua yan bàbá rẹ gẹ́gẹ́ bí akọwe rẹ.[2]
Ó forúkọ sílẹ̀ sí ilé ẹ̀kọ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àwọn obìnrin ní Katsina ó sì gba ìwé ẹ̀rí àwọn olùkọ́ Grade 2 ní ọdún 1971. Ọ jẹ olùkọ ní ẹkọ Islam atí pé o kọ́ lẹta ní èdè Gẹ̀ẹ́sì atí Lárúbáwá.[3]
Safinatu jẹ Ìyàwó Alàkóso kẹ́jẹ̀ tí Nàìjíríà láti ọgbọn ọjọ kíní Oṣù Kẹ́jìlá ọdún 1983 sí 27 Oṣù Kẹjọ ọdún 1985.[4][5] Àwọn ọmọ orilẹède Nàìjíríà ko mọ ọn nítorí pé ko ní ọfiisi tirẹ̀ tàbí òṣìṣẹ́ tí àrà ẹni ní Dodan Barracks. Ọ dúró kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn ṣùgbọ́n ọ gbá ojúṣe gbígbàlẹjọ àlejò gbígbà àwọn obìnrín àkọkọ́.[6][7][8]
Ó pàdé Muhammadu Buhari nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá (14), wọ́n sì ṣègbéyàwó ní ọdún 1971 nígbà tó pé ọmọ ọdún méjìdínlógún (18).[2][9] Wọn bí ọmọ márùn ẹyun; Zulaihatu, Magajiya-Fatima, Hadizatu-Nana, Safinatu Lami ati Musa. Nígbà tí Ibrahim Babangida tí gbàjóba Muhammadu Buhari nìjóba, o lọ́ sí Kaduna pẹlú àwọn ọmọ rẹ. Lèyìn ífípabanilópo àwọn ológun tí wọn mú Muhammadu Buhari kúrò gẹ́gẹ́ bí ààrẹ ní ọjọ kétadinlógbón oṣù kẹ́jọ odún 1985, nígbà tí wọn jáde kúrò ninú tubu, o kọ Safinatu sílẹ láìpẹ́ ní 1988;[10][4] ìdí tí Buhari fí kọ ìyàwó rẹ àkọkọ́ sílẹ̀ ní a kó mọ́. Sùgbón, a gbó pé wọn fí kán Safinatu pé ọ gbá iranlọwọ ọwọ́ lówó Babangida nígbà tí ọkọ rẹ wá ní ẹwọn pẹlú ìkìlọ ọkọ rẹ.[11][4]
Safinatu kú ní ọjọ́ 14 Oṣù Kíní ọdún 2006 nítorí àbájáde àwọn ilólu tí o ní ìbátan sí àtọgbẹ ní ọdún 53.[10][4]