Saeed Ahmad Palanpuri (tí wọ́n tún kọ gẹ́gẹ́ bí Saʻīd Aḥmad Pālanpūrī) (1940 sí ọjọ́ kọ̀kandínlógún,Oṣù igbe ọdún 2020), jẹ́ ọ̀mọ̀wé Mùsùlùmí Sunni ti ilẹ̀ Indian àti òǹkọ̀wé, èyí tí ó jẹ́ gẹ́gẹ́ bí gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá, ìyẹn Shaykh al-Hadith àti ọ̀gá ilé-ìwé Darul Uloom Deoband. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwé rẹ̀ ni wọ́n máa ń béèrè fún ní kíka ní Darul Uloom Deoband.[1][2][3]
Wọ́n bí Palanpuri ní ọdún 1940 ní abúlé Kaleda, Vadgam ni ó ń jẹ́ tẹ́lẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Palanpur. [4]Ó kàwé ní Mazahir Uloom bákan náà ni ó sì tún lọ sí Darul Uloom Deoband, níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè àbáláyé das-e-nizami [5][6] Àwọn olùkọ́ rẹ̀ ni, Muhammad Tayyib Qasmi, Syed Fakhruddin Ahmad, Ibrahim Balyawi, Mahdi Hasan Shahjahanpuri, àti Naseer Ahmad Khan.[7]
Palanpuri darapọ̀ mọ́ Jamia Ashrafiya ní Rander gẹ́gẹ́ bi olùkọ́ ní ọdún 1965, tí ó ṣiṣẹ́ olùkọ́ni fún bí ọdún mẹ́wàá.Wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ Darul Uloom Deoband ní ọdún 1973 pẹ̀lú ìdúró Manzur Nu'mani.[5][8] Ní ọdún 2008,Ó wọlé gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá, ìyẹn Shaykh al-Hadith ní Naseer Ahmad Khan ó sì tún jẹ́ ọ̀gá ilé-ẹ̀kọ́ ibẹ̀ náà.[6][9][10] Iṣẹ́ olùkọ́ni rẹ̀ ní Darul Uloom Deoband lé ní àádọ́ta níbẹ̀.[11][12]
Pratibha Patil yẹ́ Palanpuri pẹ̀lú ìwé-ẹ̀rí Ìyẹ́nisí níbi ìkẹrìnlélọ́gọ́ta àyájọ́ ọjọ́ òmìnira ilẹ̀ India. [13]
Palanpuri wòye wí pé ètò ẹ̀kọ́, èyí tí àwọn ijọ̀ba fẹ́ pèsè láti ri pé àwọn pèsè ètò-ẹ̀kọ́ tó yanranntí ní àwọn Madrasa (SPQEM) lè foríṣọ́npọ́n.
Àwọn iṣẹ́ Palanpuri' ni:[3]