Sàláwà Àbẹ̀ní Queen of Waka | |
---|---|
Orúkọ àbísọ | Salawa Abeni Alidu |
Ọjọ́ìbí | 5 Oṣù Kàrún 1961 Epe, Lagos State |
Ìbẹ̀rẹ̀ | Epe |
Irú orin | Waka music |
Occupation(s) | Musician |
Years active | (1975 –present) |
Labels | Leader records, Kollington, Alagbada |
'Sàláwà Àbẹ̀ní Álídù ni wọ́n bí ní (5 May 1961), ó jẹ́ olórin ọmọ orílẹ̀ èdè Nàj̀íríà.[1] Ó wá láti Ìjẹ̀bú etí-Òsà nị́ ìpínlẹ̀ Ògùn. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin wákà kikọ nígbà tí ó ṣe orin tó sọọ́ di ìlú-mọ̀ọ́ka tí ó pè àkọ́lé rẹ̀ ní Late General Murtala Ramat Mohammed, ní ọdún 1976, lábẹ́ ilé iṣẹ́ (Leader Records). Orin yìí ni ó jẹ́ orin àkọ́kọ́ tí obìnrin yóò kó jáde lédè Yorùbá tí ó sì tà iye tí ó lé ní Mílíọ́nù kan ní ilẹ̀ Nàìjíríà.
Àbẹ̀ní kò dá iṣẹ́ orin rẹ̀ dúró lábẹ́ ilé-iṣẹ́ 'Leader' títí di ọdún 1986, nígbà tí ó fòpin sí ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ẹni tí ó nilé iṣẹ́ Leader Records, ìyẹn Lateef Adepoju. Ó fẹ́ Olóyè Kollington Àyìnlá, tí ó sì dara pọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ ọkọ rẹ̀ tí ó sì wà pẹ̀lú ilé iṣẹ́ náà títí di ọdún 1994.
Aláàfin Ọ̀yọ́, Ọba Làmídì Adẹ́yẹmí ní ọdún 1992 dé Sàláwà Àbẹ̀ní ládé "Queen of Waka Music".[2] Orin Wákà ní ó jẹ́ orin tí ẹ̀sìn Islam kópa tó pọ̀ nínú rẹ̀ (Islamic-influenced) tí a fi àdàpọ̀ orin ìbílẹ̀ èdè Yorùbá gbé kalẹ̀. Ṣáájú Àbẹ̀ní Sàláwà, Batile Àlàkẹ́ ni ó kọ́kọ́ kọ orin náà tí ó sì sọọ́ di àgbọ́ málè lọ fún àwùjọ Yorùbá; ẹ̀ka orin yìí (Waka) ti wà tipẹ́ ṣáájú jùjú àti fuji.
Nị́gbà tí Sàláwà ń bá ilé iṣẹ́ ìròyìn kan sọ̀rọ̀. Oríṣiríṣi rúkè-rúdò ló wáyé nígbà tí gbajú-gbajà olórin náà ń gba àwọn ènìyàn níyànjú láti yàgò fún ìwà "Akọ sí Akọ" tí ó sì di ẹ̀bi ìwà náà lé ìwà lílò ògùn olóró lórí.[3] Ọ̀pọ̀ àwọn lámèyítọ́ ló sọ wípé Àbẹ̀ní sọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú "Àìmọkan".[4] Ṣùgbọ́n arábìnrin kan Ọlájùmọkẹ́ Òrìságunà tí ó jẹ́ onípolówó ló tún fan rere ọ̀rọ Sàláwà wípé: 'lábẹ́ òfin ilẹ̀ Nàìjíríà tí ó sì tún dá lórí òfin ilẹ̀ Bríténì wípé "ìbálòpọ̀ akọsákọ jẹ́ ìwà ọ̀daràn tí ó sì tọ́ sí ìjìyà lábẹ́ òfin ilẹ̀ Nàìjíríà láti ọmọ ọdún mẹ́rìnlá lọ sókè yálà kí wọ́n t̀i wọ́n mọ́lé tàbí kí wọ́n yẹjú wọn". Èyí jẹyọ nínú fídíò rẹ̀ tó fi léde nínú àpo YouTube Olajumoke Sauce 7: ní oṣù Kejì ọdún 2018.[5]