Ọ̀gbẹ́ni Salman Mazahiri (tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹwàá oṣù kẹwàá ọdún 1946 – ó kú lógúnjọ́ oṣù keje ọdún 2020) jẹ́ ọ̀mọ̀wé ọmọ orílẹ̀ èdè India tí ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Gíwá ilé-ẹ̀kọ́ gíga Mazahir Uloom Jadeed.
Wọ́n bí Mazahiri lọ́jọ́ kẹwàá oṣù kẹwàá ọdún 1946. Nígbà tó wà lọ́mọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ó wọ ilé - ẹ̀kọ́ Mazahir Uloom, Saharanpur lọ́dún 1962 (1381 AH), ó sì kàwé gboyè ní 1386 AH. Ó kàwé gboyè nínú imọ̀ Sahih Bukhari pẹ̀lú Muhammad Zakariyya Kandhlawi, Sahih Muslim, Sunan Nasai, Tirmidhi àti Munawwar Hussain, Sunan Abu Dawud pẹ̀lú Muzaffar Hussain àti Al-Aqidah al-Tahawiyyah pẹ̀lú Muhammad Asadullah.[1] Ó kàwé gboyè nínú imọ̀ studied Mishkat al-Masabih pẹ̀lú Muzaffar Hussain títí di ipele "ẹsẹ̀ gbòógì" ("major sins") ó sì parí rẹ̀ pẹ̀lú Muhammad Yunus Jaunpuri.[2]
Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Talha Kandhlawi.[3]
Mazahiri bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní Mazahir Uloom lọ́dún 1968. Ó kọ́ Tafsir al-Jalalayn lọ́dún 1972,nígbà tí ó di ọdún 1976 ó di ọ̀jọ̀gbọ́n hadith ní ilé-ẹ̀kọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn Àfáà níbi tí ó ti ń kọ́wọ̀n ní imọ̀ Mishkat al-Masabih.[2][1] Nígbà tí ó di ọdún 1992,àwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ Mazahir Uloom Jadeed yàn án ní Gíwá ilé-ẹ̀kọ́ náàa. Ó sì gorí òye náà lọ́jọ́ lọ́jọ́ ọgbọ́n oṣù keje ọdún 1996.[1][4] Talha Kandhlawi yàn án gẹ́gẹ́ bí adarí (Sajjada Nashin) ti khanqah ti Muhammad Zakariyya Kandhlawi.[3]
Ní ọdún 2007, Mazahiri tako àbá ìgbìmọ̀ àpapọ̀ Central Madrasa Board ní India.[5][6] Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ All India Muslim Personal Law Board àti Darul Uloom Nadwatul Ulama.[2]
Mazahiri kú lógúnjọ́ oṣù keje ọdún 2020.[4][7] Ààrẹ Jamiat Ulama-e-Hind, Arshad Madani kẹ́dùn ikú Mazahiri gẹ́gẹ́ bí àjálù aburú fún gbogbo Musulumi India.[8]
Mazahiri jẹ́ àna Muhammad Zakariyya Kandhlawi.[9] Olórí Tablighi Jamat Muhammad Saad Kandhlavi jẹ́ àna Mazahiri.[10]
|url-status=
ignored (help)