Samuel Olatunde Fadahunsi | |
---|---|
President of the Council for the Regulation of Engineering in Nigeria (COREN) | |
In office 1977–1986 | |
President of the Nigerian Society of Engineers (NSE) | |
In office 1967–1970 | |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Nigeria | 17 Oṣù Kẹta 1920
Aláìsí | 12 August 2014 Lagos, Lagos State, Nigeria | (ọmọ ọdún 94)
Samuel Olatunde Fadahunsi (17 March 1920 – 12 August 2014) fìgbà kan jẹ́ onímọ̀-ẹ̀rọ àti ààrẹ ẹgbẹ́ COREN, tó jẹ́ àjọ tó ń rí sí ìmọ̀-ẹ̀rọ ní Nàìjíríà.[1]
Ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹta ọdún 1920 ni wọ́n bí Samuel sí Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, tó wà ní apá Ìwọ̀-oòrùn iẹ̀ Nàìjíríà. Ilé-ìwé Saint John ní, Iloro, Ilesha, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni ó lọ, láti ọdún 1927 wọ 1936. Ó tún lọ Government College, Ibadan, láti ọdún 1937 wọ ọdún 1942. Ní ọdún 1948, ó gba ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ tó fi gba oyè bachelor's degree nínú ìmọ̀-ẹ̀rọ Civil engineering ní Battersea Polytechnic ní ìlú London.[2] Lẹ́yìn tó gba oyè ẹ̀kọ́ yìí ní ọdún 1952, ó darapọl mọ́ Cubits, tó jẹ́ ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ ní ilè Britain, ó sì ṣiṣé níbẹ̀ fún ọdún méjì.[3] Ó padà sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà níbi tí ó ti di onímọ̀-ẹ̀rọ ní kíkún.[4] Ó kúrọ̀ ní England ní ọdún 1957 fún ẹ̀kọ́ oyè PGD, gẹ́gé bí onímọ̀-ẹ̀rọ tó ń rí ọ̀rọl omi. Ó parí ẹ̀kọ́ náà ní ọdún 1958, ó sì padà sí Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí i àgbà onímọ̀ ẹ̀rọ ní àwọn ìlú tó wà ní apá Ìwọ̀-oòrùn bí i Abẹ́òkúta, Ìbàdàn àti Benin.[5] Ó padà di Chief Water Engineer ní old Western Region of Nigeria (1960-1963). Bákàn náà ni ó di Deputy Chief Executive Officer láti ọdún 1963 wọ ọdún 1965 àti Chief Executive Officer, Lagos Executive Development Board (LEDB), now Lagos State Development and Property Corporation (LSDPC) (1965-1972).[6][7][8] Ó tún ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i Chairman of Industrial Research Council of Nigeria láàárín ọdún 1971 àti 1974[9]
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)