Sayyid Muhammad Abid (tí a tún mọ̀ sí Hāji Abid Hussain) (1834–1912) jẹ́ ọ̀mọ̀wé mùsùlùmí ará Íńdíà kan tó dá Darul Uloom Deoband sílẹ̀. Ó jẹ́ Igbákejì Alákoso ti Darul Uloom Deoband fún ìgbà mẹ́ta.
Abid Hussain ni a bí ní ọdún 1834 ní Deoband, Mughal India, nínú ìdílé tí ó ní ìran sí Hussain nípasẹ̀ Ja’far al-Sadiq.[1][2][3] Nígbà tí ó di ọmọ ọdún méje, ó kọ́ ẹ̀kọ́ Al-Qur'an àti èdè Persia ní Deoband. Ó lọ sí Delhi fún ẹ̀kọ́ gíga. L'ákọ̀ọ́kọ́, ó ní láti padà sí Deoband nítorí àwọn ọ̀ràn ìlera ti bàbá rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, bàbá rẹ̀ kú lẹ́hìn ọjọ́ díẹ̀ èyí tí ó jẹ́ kí ó dá ẹ̀kọ́ rẹ̀ dúró.[4] Wọ́n fun ní àṣẹ ní Tasawwuf nípasẹ̀ Imdadullah Muhajir Makki àti Karim Bakhsh Rampuri.
Abid Hussain jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Olùdásílẹ̀ ti Darul Uloom Deoband.[5] Lákọ̀ọ́kọ́, ó yàtọ̀ sí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó dá sílẹ̀ nípa ìyapa “madrasa” kúrò ní Jama Masjid, ó sì pinnu pé “madrasa” náà gbọ́dọ̀ dúró ṣinṣin ní Jama Masjid. Ó yí èrò rẹ̀ padà lẹ́hìn náà [4] ó sì jẹ́ ènìyàn kejì tí ó fi ìpìlẹ̀ ilé titun Darul Uloom Deoband lé'lẹ̀ lẹ́hìn tí òkuta àkọ́kọ́ ti lélẹ̀ nípasẹ̀ Miyanji Munne Shah. Àṣẹ-títà ilẹ̀ tí ilé tuntun tí a kọ́ ilé-ẹ̀kọ́ "seminary" Deoband sí ni a fún lórúkọ ojú-rere rẹ̀.[5]
Ó ṣe ìránṣẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga Deoband gẹ́gẹ́ bí igbákejì alákoso fún ìgbà mẹ́ta. Ní àkọ́kọ́, láti ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní ọdún 1866 sí 1867. Ìgbà kejì láti ọdún 1869 sí 1871 àti ìgbà kẹ́ta láti ọdún 1890 sí 1892.[6] Ó tún jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ti ẹgbẹ́ alákoso àkọ́kọ́ ti Darul Uloom Deoband.
Abid Hussain kú ní ọdún 1912 ní Deoband.[2] Lára àwọn ọmọ-lẹ́hìn rẹ̀ ni Aziz-ur-Rahman Usmani.[7]