Shaleen Surtie-Richards | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 7 Oṣù Kàrún 1955 Upington, Cape Province, South Africa |
Orílẹ̀-èdè | South African |
Iṣẹ́ | Actress, talk show host |
Ìgbà iṣẹ́ | 1974-present |
Gbajúmọ̀ fún | Fiela se kind, Egoli: Place of Gold, Supersterre |
Shaleen Surtie-Richards (bíi ni ọjọ́ keje, oṣù karùn-ún, ọdún 1955)[1] jẹ́ òṣèré ni orílẹ̀ èdè South Áfríkà. Ó gbajúmọ̀ fún ipá tí ó kó nínú eré Fiela se Kind ni ọdún 1988 àti Egoli: Place of Gold.
Wọ́n bíi Shaleen sí ìlú Upingtong ni orílẹ̀ èdè South Áfríkà. Bàbá rẹ̀ jẹ́ olùdarí ilé ẹ̀kọ́, ìyá rẹ sì ju olùkọ́.[2][3] Surtie-Richards jẹ́ olùkọ́ fún àwọn ọmọdé láti ọdún 1974 di ọdún 1984. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré ṣíṣe ni ọdún 1984.
Surtie-Richard ṣe adájọ́ fún ètò Supersterre láti ọdún 2006 di ọdún 2010.
Surtie-Richard tí gbà àmì ẹ̀yẹ tó lé ní ogójì. Ó gbà àmì ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bíi òṣèré tó dára jù lọ láti ọ̀dọ̀ Fleur du Cap Theatre Awards fún ipá Hester tí ó kó nínú eré Hallo en Koebaai (Hello and Goodbye). Ní ọdún 2009, ó gbà ẹ̀bùn míràn láti ọ̀dọ̀ Fleur du Cap Awards fún ipá tí ó kó nínú eré Shirley Valentine ni ọdún 2008. Ní ọdún 2018, ó gbà ẹ̀bùn eléré tó gbajúmọ̀ láti ọ̀dọ̀ Herrie Prize níbi ayẹyẹ Klein Karoo Arts Festival.[8] Ní ọdún 2014, ó gbà ẹ̀bùn fún akitiyan rẹ tí ó tí kó nínú àwọn eré bíi Egoli: Place of Gold, Generations, and 7de Laan.[9] Wọn yàán kalẹ̀ fún ẹ̀bùn òṣèré tó tayọ julọ ni ọdún 2014.[10] O gba ebun láti ọ̀dọ̀ Naledi Theater Awards ni ọdún 2015.[11]