Stanley Ejike Awurum (Ti bi ọjọ kerinlelogun Osu Kefa ọdun 1990) je agbaboolu orilẹ-ede Naijiria ti o n gba iwaju fun egbe agbaboolu Varzim ni orilẹ-ede Portugal. In yo
A bi ni Mbieri, Ipinle Imo, Awurum bẹrẹ iṣẹ agba rẹ ni Mozambique, nibiti o ti jẹ agbaboolu ti o ga julọ pẹlu goolu mejilelogun fun FC Chibuto ti o wa ninipin keji ni 2013. Ni Oṣu Kini ọdun 2015, o darapọ mọ Varzim SC ti ipele kẹta Portuguese pelu eto iya awin oṣu mẹfa kan. [1] Ni ipari rẹ, pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu re lati Póvoa de Varzim bayi ti o ti ni igbega si Segunda Liga, o fowo si iwe adehun ọdun meji. [2]
Ni akoko ọjọgbọn akọkọ rẹ, Awurum ti gba goolu mokanla ninu ifẹsẹwọnsẹ mejilelogiji, ti o fi di ikẹta ninu awọn agbabọọlu ti o ga julọ lẹhin ẹlẹgbẹ rẹ Simeon Nwankwo ti Gil Vicente FC ati Platiny ti CD Feirense . [3] Ni kete ti o pari ni Oṣu Karun ọdun 2016, o darapọ mọ Portimonense SC fun ọdun kan pẹlu aṣayan ti mẹta diẹ sii, didanu eto lati Primeira Liga club SC Braga lati duro ni ipele keji. [4] [5]
Lehin ti o ti kopa diẹ ninu Ife eye LigaPro ti Portimonense ni ọdun 2016 – 17 ati ifarahan mẹta nikan bi aropo, wọn ya Awurum pada si Varzim ni ipari Oṣu kejila ọdun 2017, pelu agbabọọlu Omo Brazil yi n je Buba . [6] Igbesẹ yii jẹ igba pipẹ, ati ni Oṣu Kini ọdun 2019 o ti ya l'awin kọja si ipele keji si CD Cova da Piedade fun oṣu mẹfa. [7]
Ni oṣu keji ọdun 2021, Awurum lọ silẹ si ipele kẹta si Campeonato de Portugal ni ọmọ ọdun ogbon, lati gba bọọlu fun SC Salgueiros . [8]