Sthandiwe Kgoroge | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Sithandiwe Msomi 4 Oṣù Kejì 1972 |
Orílẹ̀-èdè | South Africa |
Ẹ̀kọ́ | University of Natal |
Iṣẹ́ | Òṣèré |
Olólùfẹ́ | Tony Kgoroge |
Sthandiwe Kgoroge (bí ní Sithandiwe Msomi; Ọjọ́ kẹ́rin oṣù kejì ọdún 1972)[1] jẹ́ òṣèré South Africa tó farahàn ní Generations, eré-ẹlẹ́lẹsẹ apá karùn-ún àti kejé ní MTV Shuga, eré-ẹlẹ́lẹsẹ kékeré MTV Shuga Alone Together, àti eré-ẹlẹ́lẹsẹ àkọ́kọ́ ti Yizo Yizo.
Kgoroge gbé ní Edmonton, Canada, láti ọmọ ọdún márùn-ún títí di mẹ́wàá.[2] Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní University of Natal, níbi tó ti parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ìmọ̀ eré-oníṣe.[3] Ó wí pé òun gbìyànjú lórí bí òun ṣe rí ara òun lójú, ṣúgbọ̀n ó padà rí wí pé àwọ̀ dúdú òun dára.[4]
Ó ṣe àfihàn eré-ẹlẹ́lẹsẹ àkọ́kọ́ ti Yizo Yizo bí Zoe Cele ni ọdún1999. Ó dá a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré tó ṣe igi lẹ́yìn ọgbà jù nínu eré-ẹlẹ́lẹsẹ oníṣe fún ipa yìí tó kó níbẹ̀, àti wí pé ó gba Avanti Award.[3] Ó ṣe ìbejì ní Generations[4] láti ọdún 1998 títí di ọdún 2005.
Ó ṣe ìfarahàn ní eré-ẹlẹ́lẹsẹ apá karùn-ún MTV Shuga Gẹ́gẹ́ bí i Aunt Nomalenga àti wí pé ó padà fún ipa náà ní eré-ẹlẹ́lẹsẹ kékeré.
Ìgbé àyè ìkọ̀kọ̀
MTV Shuga Alone Togethertó ṣe àfihàn ìṣòro àjàkálẹ̀ àrùn e COVID-19 pandemicni ọjọ́ ogún oṣù kẹ́rin ọdún n02020.[5]Nígbà tí Wọ́n ń ṣe eré-ẹlẹ́lẹsẹ yìí, àwọn ẹ̀dá-ìtàn yìí bá ará won sọ̀rọ̀ nípa ìtìmọ́lẹ́ tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà àjàkálẹ̀ àrùn yìín.[6] Wọ́n ṣe eré yìí ni Nàìjíríà, South Africa, Kẹ́ńyà àti Cote D’Ivoire. Tí gbogbo bí Wọ́n ṣe ń ṣe eré náà wà lọ́wọ́ àwọn òṣèré yìí náà fún ara wọn,[5] w tí a rí erato Walaza, Mamarumo Marokane aàtiMohau Cele.
Kgoroge fẹ́ òṣèré tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tony Kgoroge,[3] àti wí pé wọ́n bímọ pẹ̀lú. Wọ́n di ẹni tí ó bọ́ nínu gbèsè ni ọdún 2018, ó wí pé àwọn ọmọ ènìyàn gbàgbé òun àti ìyàwó òun lórí ínsítígáràmì, wí pé "ará-ìlú lásán" ni wọ́n .[7] Ó ti ẹni tó pàdánù owó púpọ̀ nítorí wí pé àwọn tó máa ń ìròyìn ò sọ owó rẹ̀ fún àsìkò kan léraléra.[7]
|url-status=
ignored (help)