TY Bello

Toyin Ṣókẹ́fun-Bello (ọjọ́ ìbí - ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kíní ọdún 1978[1]), tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí TY Bello, jẹ́ ọmọ orílè-ẹ̀dẹ̀ Nàìjíríà, akọrin ni, a sì tún máa ṣe àgbékalẹ̀ orin fún àwọn ẹlòmíràn lá ti kọ́ ọ jáde, ayàwòrán ni, ó sì tún jẹ́ elẹ́yinjú àánú. Kí ó tó di àkókò tí TY Bello bẹ̀rẹ̀ isẹ́ àdáṣe rẹ̀, ó ti wà pẹ̀lú ẹgbẹ́ olórin ẹ̀mí tí a n pè ní Kush kí ẹgbẹ́ náà tó kó igbá wọlé. TY Bello jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ àgbáríjọ àwọn olùyàwòrán ní orílè-èdè Nàìjíríà, tí a n pè ní Depth of Field. TY Bello di gbajúgbajà nípasẹ̀ àwọn orin àdákọ rẹ̀ tí ó ṣe bíi "Greenland (Ilẹ̀ ọlọ́ọ̀rá)", "Ẹkùndayọ̀", "This Man (Ọkùnrin Yìí )", "Freedom (Òmìnira)" àti "Fúnmiṣe".

[[Ẹ̀ka:Àwọn ènìyàn alààyè|Àwọn olórin ilẹ̀ Nàìjíríà]]