Taiwo Abioye | |
---|---|
Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmò Englisi ní Covenant University | |
In office 2013–2016 | |
Ígbákejì adarí at Covenant University | |
In office 2012–2016 | |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 17 Oṣù Kínní 1958 Ipinle Kaduna |
Residence | Canaanland, Ipinle Ogun |
Alma mater | Ahmadu Bello University (Bachelor of Education in Language Arts) Ahmadu Bello University ( Master of Arts in English) Ahmadu Bello University (Doctor of Philosophy in English) |
Taiwo Olubunmi Abioye jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ Englisi ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni obìnrin àkọ́kọ́ láti di Ìgbàkejì adarí Covenant University.[1]
A bí Taiwo ní ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gún oṣù kínní ọdun 1958, ní Kaduna sínú ìdílé àwọn òbí tó wá láti Ìpínlẹ̀ Ogun, Abioye gba àmì-ẹ̀yẹ àkọ́kọ́ nínú ìmò Language Arts Yunifásítì Àmọ́dù Béllò. Bákan náà ẹ̀wẹ̀, ó tẹ̀síwájú láti gba àmì-ẹ̀yẹ Master àti ti Dókítá ní ilé-ìwé kan náà ní ọdun 1992 àti 2004.[2] Ní ọdun 1982, Abioye gba àmì-ẹ̀yẹ akẹ́kọ̀ọ́ tó mọ̀wé jùlọ ni ẹ̀ka Inglisi ti Yunifásitì Àmọ́dù Béllò.[3]