Taiwo Ajai Lycett | |
---|---|
Taiwo Ajai-Lycett, OON | |
Ọjọ́ìbí | Lagos, Western Region, British Nigeria | 3 Oṣù Kejì 1941
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian (1941 – present) |
Iṣẹ́ | Television presenter film actress cosmetologist journalist |
Taiwo Ajai-Lycett (bíi ọjọ́ Keta oṣù kejì ọdún 1941) ni òṣeré, oníròyìn àti atọ́kùn ará ilẹ̀ Nàìjíríà.[1][2] Ajai-Lycett ni obìnrin àkọ́kọ́ tí ó ṣe iṣẹ́ olóòtú ìwé-ìròyìn Africa Woman ni ọdún 1970.[3]
Wọn bí Lycett ni ọjọ́ Keta oṣù kejì ọdún 1941 ni ìpínlè Èkó,[4] bàbà rẹ jẹ ọmọ ìran Àwórì.[5] Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Mt Carmel Convent School àti Methodist Girl's High School ni ìpínlè Èkó.
Ó lọ sí ìlú London láti ka ìwé ímo Business and administration. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Hendon College of Technology nibẹ ni ó ti gba HND nínú Business Studies ni ọdún 1969.[6] [7] Ní Igba tí ó wà ní ilẹ̀ ẹ̀kọ́ gíga, ó ń ṣíṣe ni Lyson tea shop, ilé ifiwe ranse ati ilé iṣẹ́ ìpolówó.[8]
O bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ sì ní ṣe ère ni ọdún 1966 ni gba ti o kópa nínú eré The lion and the jewel. Kò lérò láti kópa nínú eré na tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n olùdarí eré náà, William Gaskill sọ fún pé kí ó wà kópa nínú eré náà. Lẹ́yìn eré náà ni ó wà lọ sí ilé ẹ̀kọ́ orin àti eré tí "Guildhall School of Music and Drama".
O kópa nínú àwọn ère orí ìtàgé bíi Life everlasting , The national health àti Parcel post. [9][10]O tí kópa nínú àwọn eré tí Nàìjíríà bíi Tinsel àti Olibiri.[11]
Ní ọdún 1975, Lycett darapọ̀ mọ àwọn òṣìṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ Africa Magazine.O jẹ ọmọ ẹgbẹ́ Society of Nigerian Theatre Artists (SONTA).[12]
Ni ọjọ́ kìíní oṣù kẹwàá ọdún 2006, Lycett gba ebun Officer of the Order of Niger láti ọwọ́ Chief Olusegun Obasanjo.[13][14] Ní oṣù kejì ọdún 2008, wọn fi ṣe olórí British-African theatre, pelu Dotun Adebayo àti Yemi Ajíbádé.[15]
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)