Tanimowo Ogunlesi | |
---|---|
Fáìlì:Photo of Tanimowo Ogunlesi (cropped).png | |
Ọjọ́ìbí | 1908 |
Aláìsí | 2002 |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Ẹ̀kọ́ | London University |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Kudeti Girls School Ibadan United Missionary College (UMC) |
Iṣẹ́ | Women's rights activist |
Gbajúmọ̀ fún | Leader of the Women's Improvement League |
Tanimowo Ogunlesi (1908-2002[1]) jẹ́ ajàfẹ́ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin ilẹ̀ Nàìjíríà ó tún jẹ́ adarí Women's Improvement League[2][3]. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn adarí tó ń já à fún ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin àti ọ̀kan lára àwọn olùdásílẹ̀ National Council of Women Societies, tí ń ṣe aṣáájú iléeṣẹ́ ajàfẹ́ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin ti Nàìjíríà.
Tanimowo Ogunlesi lọ iléèkọ́ Kudeti Girls School Ibandan. Ó tún kàwé ní iléèkọ́ United Missionary College (UMC) fún ìkàwágboyè ìkẹ́ẹ̀kọ́ gẹ́gẹ́ bí i olùkọ́. Ó jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láti ṣe ìdásílẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ oníléégbèé ní ìlú Ìbádàn (Children Home School).
Ó jẹ́ ààrẹ àkọ́kọ́ ti National Council of Women Societies ní ọdún1959[4]. Ó ṣiṣẹ́ ribiribi lórí ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin láti ma dìbò àti láti ní àǹfààní sí àwọn ohun-èlò ẹ̀kọ́, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí i ọ̀pọ̀ àwọn adarí obìnrin ìgbà ayé rẹ̀, Kò ní ẹjọ́ tó tako sí àwọn ọkùnrin gẹ́gẹ́ olórí àwọn ìdílé oríléèdè ilẹ̀ Nàìjíríà.[5][6]