Thando Thabethe | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 18 Oṣù Kẹfà 1990 Johannesburg, Gauteng, South Africa[1] |
Orílẹ̀-èdè | South African |
Orúkọ míràn | Thando Thabooty |
Ẹ̀kọ́ | Mondeor High School |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Johannesburg |
Iṣẹ́ |
|
Ìgbà iṣẹ́ | 2003-present |
Gbajúmọ̀ fún | My Perfect family Generations |
Website | thandothabethe.com |
Thando Thabethe (bíi ni ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹfà ọdún 1990) jẹ́ òṣèré, DJ[2], agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ati àmbásẹ́dọ̀ àkókò láti ilẹ̀ Áfríkà fún Nivea. Ó ṣe atọkun fun ètò Thando Bares All lórí Channel TLC. Ó kọ ipa Nolwazi Buzo nínú eré Generations: The Legacy láti ọdún 2014 di ọdún 2017[3]. Ó jẹ́ DJ lórí rádíiò fún 5FM[4]. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orí rádíiò ni ọdún 2008 ni ilé iṣẹ́ UJFM kí ó tó padà lọ sí ilé iṣẹ́ YFM ni ọdún 2011. Ó darapọ̀ mọ́ 5FM ni ọdún 2013. Ó kó ipa Thando Nkosi nínú eré My Perfect Family[5]. Ó kópa nínú eré Mrs Right Guy.[6] Ní ọdún 2016, ó ṣe atọkun fun ayẹyẹ South African Music Awards.[7] Ní ọdún 2017, òun náà sì ni ó tún ṣe atọkun fún South African Film and Television Awards.[7] Ni ọdún 2018, ó kó ipa Linda Ndlovu nínú eré Housekeepers.[8] Ní ọdún 2019, ó kó ipa Zinhle Malinga nínú eré Love Lives Here.[9] Ní ọdún 2019, wọn yàán kalẹ̀ fún àmì ẹ̀yẹ atọkun ètò to dára jù lọ àti ètò ọ̀rọ̀ tó dára jù lọ, ó sì gba àmì ẹ̀yẹ ètò ọ̀rọ̀ tó dára jù lọ.[10]