Guardian logo.png | |
---|---|
Type | Daily newspaper |
Format | Broadsheet |
Publisher | Guardian Newspapers Limited |
Founded | 2 February 1983 |
Language | English |
Headquarters | Lagos |
Official website | guardian.ng |
The Guardian jẹ́ ìwé-ìròyìn ojoojúmọ́ olómìnira ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí wọ́n dá sílẹ̀ ní ọdún 1983,èyí tí Ilé-iṣẹ́ ìwé-ìròyìn Guardian tó wà ní ìpínlè Eko, ní Nàìjíríà.[1]
Ilé-iṣẹ́ ìwé-ìròyìn The Guardian jẹ́ dídá sílẹ̀ ní ọdún 1983 láti ọwọ́ Alex Ibru, ẹni tí ó jẹ́ oníṣòwò àti Stanley Macebuh tó jẹ́ akọ̀ròyìn pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ ìwé-ìròyìn Daily Times ti wọ́n dá ilé-iṣẹ́ yìí sílẹ̀ láti máa ṣe àgbéjáde ìròyìn tó kúnjú òṣùwọ̀n jáde pẹ̀lú àwọn olóòtú tó jí pépé.[2] Wọ́n kọ́kọ́ ṣe àgbéjáde ìwé-ìròyìn yìí ní ọjọ́ kejìlélógún, oṣù kejì, ọdún1993 gẹ́gẹ́ bíi ìwé-ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, tó máa ń jáde ní ọjọ́ Àìkú.[3]
Lásìkò ìṣèjọba Muhammadu Buhari, àwọn ajábọ̀-ìròyìn, ìyẹn Tunde Thompson àti Nduka Irabor ni wọ́n rán lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ní ọdún 1984 lábẹ́ ìfilélẹ̀ kẹrin ti ọdún 1984, èyí tẹrí òmìnira àwọn akọ̀ròyìn mọ́lẹ̀.[4][5]
|url-status=
ignored (help)