The Village Headmaster | |
---|---|
Genre | Drama |
Written by | Olusegun Olusola |
Directed by | Dejumo Lewis |
Starring | Ted Mukoro (Headmaster #1) Femi Robinson (Headmaster #2) Justus Esiri (Headmaster #3) Chris Iheuwa (Headmaster #4) |
Country of origin | Nigeria |
Original language(s) | English Yoruba Nigerian Pidgin |
Production | |
Executive producer(s) | Olusegu Olusola |
Producer(s) | Sanya Dosunmu, Dejumo Lewis |
Production location(s) | Nigeria |
Running time | 45 minutes |
Release | |
Original network | NTA |
Original release | 1964 |
The Village Headmaster (ltí wọ́n padà sọ di The New Village Headmaster) jẹ́ fíìmù àgbéléwò ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí Olusegun Olusola gbé kalẹ̀, èyí tí Dejumo Lewis ṣàgbéjáde.[1][2] Láti ìbẹ̀rẹ̀, ètò orí rédíò ní ó jẹ́, tí ó wá padà di èyí tí wọ́n ń ṣá̀fihàn ní orí NTA láti ọdún 1968 wọ ọdún 1988.[3] Lára àwọn òṣèrẹ́ tó kópa nínú fíìmù yìí ni Ted Muroko, tó jẹ́ olórí ilé-ìwé náà láti ìbẹ̀rẹ̀.[4][5] FÍìmù yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àṣeyọrí tó wáyé nínú àwọn fíìmù tí wọ́n ń ṣàfihàn lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán, ní orílẹ̀-èdè náà[6]
Ní ọdún 2021, wọ́n bẹ̀rẹ̀ àgbéjáde fíìmù náà, pẹ̀lú Chris Iheuwa gẹ́gẹ́ bí olórí ilé-ìwé tuntun.[7]
Ilẹ̀ Yorùbá, ní ìlú Oja ni ìbùdó ìtàn fíìmù yìí, tí ìtàn náà sì dá lórí ìṣẹ̀lẹ̀ inú àwùjọ àti ipa tí àwọn ìfilélẹ̀ ìjọba ìlú Oja ń ní sí i. Wọ́n ṣàgbéjáde fíìmù yìí lẹ́yìn tí Nàìjíríà gba òmìnira, ó sì jẹ́ fíìmù orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòran àkọ́kọ́ tó ní àwọn akópa láti ẹ̀yà oríṣiríṣi tó wà ní Nàìjiríà. Wọ́n lo pidgin English mọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì gan-an gan.
(Orísun[8])
Wọ́n ṣàgbéjáde eré-oníṣe yìí ní ọdún 1958, ó sì wà gẹ́gẹ́ bí ètò orí rédíò kí ó tó wá di ètò oeí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán ní NBC TV Lagos (tó wá di NTA). Ó bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu ní ọdún 1968 pẹ̀lú apá mẹ́tàlá títí wọ ọdún 1988.[11]
|url-status=
ignored (help)