Tokunbo Afikuyomi je aṣojú-ṣòfin ni Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin orílẹ̀èdè Nàìjíríà lọ́dún 1999 sí ọdún 2003. Tokunbo Afikuyomi jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà, tí ó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ sẹ́nétọ̀ tí ó ń ṣojú ẹ̀kùn gbùngbùn Èkó ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ìjọba olómìnira ìkẹrìn lábẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú AD (Alliance for Democracy).[1] Ọdún 1999 ni ó gun orí àléfà. Ó pààrọ̀ ẹ̀kùn ní oṣù Igbe ní ọdún 2002 kúrò ní gbùngbùn lọ sí apá àríwá, lẹ́yìn tí Sẹ́nétọ̀ Wahab Dosunmu ṣídìí lọ sí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |