Tọ́pẹ́ Tedela | |
---|---|
Tedela at the 2020 Africa Magic Viewers Choice Awards | |
Ọjọ́ìbí | Temitope Christopher Tedela Ìpínlẹ̀ Èkó |
Ẹ̀kọ́ | University of Lagos |
Iṣẹ́ | Òṣèré |
Ìgbà iṣẹ́ | 2006–present |
Temitope Christopher Tedela tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Tọ́pẹ́ Tedela jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé àti olùgbéré-jáde ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2][3]
Wọ́n bí Tọ́pẹ́ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí àwọn òbí rẹ̀ sí ìlú Èkó [4]Àwọn òbí rẹ̀ jẹ́ ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Èkìtì [5] Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ girama ti Model College, tí ó wà ní ìlú Mẹran ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè akọ́kọ́ nínú ìmọ̀ Mass Communication ní ilé-ẹ̀kọ́ fásitì Ìpínlẹ̀ Èkó.[6]
Ó ti gba ọ̀pọ̀ amì-ẹ̀yẹ fún àeọn iṣẹ́ takun takun tí ó ń gbé ṣe ní inú agbo àwọn òṣèré Nollyeood. Lára awọn amì-ẹ̀yẹ yí ni: Africa Magic Viewers Choice Award, Nigeria Entertainment Award, Best of Nollywood Award àti Nollywood Movies Award. Wọ́n i wo àwọn eré ọlọ́kan-ò-jọkan tí Tades ti gbé jáde ní àwọn sinimá káàkiri ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ ati ní òkè òkun bíi Cannes Film Festival, Toronto International Film Festival àti BFI London Film Festival. Lára àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti gbé jáde ni: The Lost Okoroshi (2019), What Lies Within (2017), Slow Country (2017), Ojukokoro (2017), Suru L'ere (2016), Out of Luck (2015), A Soldier's Story (2015) àti A Mile from Home tí ó jẹ́ eré tí ó ti fi gba amì-ẹ̀yẹ oríṣiríṣi.
Nígbà tí ó kẹ́kọ́ nílé ẹ̀kọ́ fásitì lọ́wọ́, Tọ́pẹ́ kópa lààmì-laaka nínú eré àtìgbà-dégbà onípele tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Edge of Paradise.[7] Ó jáwọ́ nínú ìkópa nínú eré fúngbà díẹ̀ láti lè fojú sínẹ̀kọ́ rẹ̀ , lẹ́yìn tí ó sì kàwé já, ó ṣiṣẹ́ fúgbà díẹ̀ ní ilé iṣẹ́ rédíò ti UNILAG FM.[8] [9] Tọ́pẹ́ fìgbà kan rí ṣe olóòtú ètò lórí ìkanì NTA. Ó ti kópa nínú àwọn eré oríṣiríṣi.[10][11] Ó kópa nínú eré, A Mile from Home.[12] Ní ọdún 2015, Tọ́pẹ́ tún kópa nínú eré A Soldier's Story àti eré Out of Luck. Ipa rẹ̀ tí ó kó nínú eré Suru Le're ní ọdún 2016, gẹ́gẹ́ ẹ̀dá ìtàn Kyle Steven-Adedoyin jẹ́ kí awọn ènìyàn ó fẹ́ láti máa wo eré tí ó bá ti kópa. [13][14] Tọ́pè kópa nínú eré apanilẹ́rín kan tí wọ́n pè Ojúkòkòrò àti Slow Country ní ọdún 2017.[15]Ó tún di gbajú-gbajà olùgbéré-jáde pẹ̀lú eré tìrẹ ty ó gbé jáde tí ó pe àkọ́lé rẹ̀ ní What Lies Within.[16]Ní ọdún 2018, kópa nínú eré ọ̀daràn kan tí akọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Knock Out Blessing. Ó tú kópa bí ẹ̀dá-ìtàn Dr. Dauda nínú eré The Lost of Okoroshi[17] Tedela tún kópa nínú eré tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ The Ghost and the House of Truth. [18]
Ní ọdún 2016, wọ́n fi Tọ́pẹ́ Tedela ṣe aṣojú fún ilé-iṣẹ́ Global Rights, ilé-iṣẹ́ tí ó ń rí sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn láti lè jẹ́ kí ó lè ṣe ìpolongo tako ìwà ìfipábánolòpọ̀ awọn ọmọ obìnrin ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [19]
Ọdún | Amì-ẹ̀yẹ | Ìsọ́rí | Iṣẹ́ | Èsì |
---|---|---|---|---|
2017 | Best of Nollywood Awards | Best Actor in a Supporting Role | Slow Country | Yàán |
2016 | City People Entertainment Awards | Best Actor in a Supporting Role | Suru L'ere | Yàán |
Nigeria Entertainment Awards | Best Actor in Supporting Role | Yàán | ||
2014 | 10th Africa Movie Academy Awards | Most Promising Actor | A Mile from Home | Yàán |
2014 Africa Magic Viewers Choice Awards | Best Actor In A Drama | Gbàá | ||
2014 Best of Nollywood Awards | Best Actor in a Leading Role (English)[20] | Gbàá | ||
Revelation of the Year (Male) | Yàán | |||
2014 Golden Icons Academy Movie Awards | Most Promising Actor | Gbàá | ||
Best On-Screen Duo | Yàán | |||
2014 Nigeria Entertainment Awards | Best Actor in a Lead Role | Gbàá | ||
2014 Nollywood Movies Awards | Best Actor in a Leading Role (English) | Yàán | ||
Best Rising Star (Male) | Gbàá | |||
2014 Express Star Awards[21] | Rising Star | Himself | Gbàá |
Ọdún | Àkọ́lé | Ipa tí ó kó | Notes |
---|---|---|---|
2007 | Twisted | Sola | |
2013 | Awakening | ||
2013 | Torn | Young Olumide | |
2013 | A Mile from Home | Lala/Jude Odaro | |
2013 | Cyanide | Emeka | Short Film |
2014 | Another Day to Die Young | Comrade | TV Film |
2014 | Birthday Bash | Scoda | |
2014 | Leeway | Chuks | Short Film |
2015 | Lunch Time Heroes | Deji | with Omoni Oboli & Dakore Akande |
2015 | Apostates | Osas | |
2015 | A Soldier's Story | Major Egan | |
2015 | Out of Luck | Dayo | |
2016 | Suru L'ere | Kyle Stevens Adedoyin | with Rita Dominic |
Ojukokoro (Greed)[22][23] | Sunday | ||
2017 | King Invincible | Taari | with Gabriel Afolayan |
Slow Country | Osas | with Majid Michel | |
What Lies Within[24] | Gboyega | Also Producer | |
2018 | Knock Out Blessing | Yomi | |
2019 | The Lost Okoroshi | Dr Dauda | |
2019 | The Ghost and the House of Truth | Barrister Tokunbo |
Ọdún | Àkòrí | Ipa tí ó kó | Àríwísí |
---|---|---|---|
2006 | Edge of Paradise | Julian | |
2008 | My Mum & I | June | |
2008 | Super Story (Omojuwa) | Tesiro | |
2012 | Burning Point | ||
2012 | Tweeters | Kunle | |
2013 | Super Story (The Secret) | Tai | |
2014 | Oasis [25] | Oreva | |
2015 | The Team (TV series) | Efe | |
2016 | Jamestown | Lucky | |
2017 | Jemeji | Obi | Chief |
2019 | Powder Dry | Arthur | |
2019 | Underbelly | Nonso |
Ọdún | Àkòrí | Ipa tí ó kó | Notes |
---|---|---|---|
2011 | Man Talk, Woman Talk | Emeka | |
2014 | Diagnosis | Emeka | |
2014 | The Agency | Fawaz | |
2019 | The Mistress of Wholesome | Nengak Josiah | |
2019 | The Wives | Lawyer | |
2019 | Whumanizer | Tunde Bridges |
|website=
(help)