Turai Yar'Adua | |
---|---|
Aya Ààrẹ-àná, Umar Musa Yar'Adua | |
In role Ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2007 – Ọjọ́ karùn-ún, oṣù karùn-ún ọdún 2010 | |
Ààrẹ | Umaru Yar'Adua |
Asíwájú | Stella Obasanjo |
Arọ́pò | Patience Jonathan |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 26 Oṣù Keje 1957 Ìpínlẹ̀ Katsina |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Umaru Yar'Adua (1975–2010; his death) |
Àwọn ọmọ | Ọmọbìnrin márùn-ún, okùnrin méjì |
Alma mater | Ahmadu Bello University |
Turai Yar'Adua tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù keje ọdún 1957,(26 July 1957)[1] jẹ́ opó sí Ààrẹ-àná tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ẹni tí ó tún jẹ́ Gómìnà-àná Ìpínlẹ̀ Kàtsínà, Umaru Musa Yar'Adua. Òun ní Obìnrin Àkọ́kọ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́dún 2007 títí ọkọ rẹ̀, Ààrẹ-àná, Yar'Adua fi ta téru nípàá lọ́jọ́ karùn-ún oṣù karùn-ún ọdún 2010.
Wọ́n bí Turai Yar'Adua ní Ìpínlẹ̀ Kàtsínà lápá àríwá Naijiria lóṣù keje ọdún 1957.[1] Ó kàwé ní Government Girls Secondary School ní Kankiya nígbà èwe rẹ̀.[1]
Turai Yar'Adua kàwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ ní Garama Primary School ní Katsina, tí ó sìn kẹ́kọ̀ọ́ girama ní ní Government Secondary School ní Kankia, ní Ìpínlẹ̀ Kàtsínà bákan náà. Lẹ́yìn náà, ó kàwé ní Katsina College of Arts, Science and Technology ní Zaria, ní Ìpínlẹ̀ Kàdúná, níbi tí wọ́n ti sọ pé òun ní akẹ́kọ̀ọ́ tó mọ̀wé jù nígbà náà lọ́dún 1980.[1] In 1983, Yar'Adua received a bachelor's degree in Language from Ahmadu Bello University.[1][2]