Uzoamaka Aniunoh | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Onitsha |
Orílẹ̀-èdè | Naijiria |
Ẹ̀kọ́ | Yunifasiti Naijiria, Yunifasiti Birmingham |
Iṣẹ́ | osere |
Uzoamaka Doris Aniunoh jẹ́ ònkọ̀wé àti òṣèré ará ìlu Nàìjíríà. Ó ti di òdú tí kìń ṣe àìmọ̀ fólóko nínu eré MTV Shuga léyìn tí ó ti hàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀yà eré tẹlifíṣọ́nù náà tó fi mọ́ àkọ́kọ́ àti ẹ̀kẹfà.
Aniunoh ni a bí ní Onitsha. Ó kẹ́ẹ̀kọ́ Yunifásitì ti Nàìjíríà, ní ílu Nsukka. Ní ọdún 2015, ó lọ sí UK níbití ó ti kẹ́ẹ̀kọ́ Ìwé kíkọ nì Yunifásitì Birmingham tí ó sì gba oyè gíga.[1]
Ó padà sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún 2017, ó sì lọ sí àwọn àyẹ̀wò tí ó ṣí sílẹ̀ fún ti eré alátìgbà-dègbà tuntun tí a pè ní MTV Shuga. Ó ṣe kòńgé láti wà lára àwọn tí wọ́n yàn, ó sì kópa Cynthia. Ó ti gba ìmọ̀ràn tẹ́lẹ̀ rí láti ẹnu Níyì Akinmolayan ní im̀uŕasílẹ̀ fún àyẹ̀wò naa. Irú ìmọ̀ràn yí kan náa ̀ni ó ṣé ní ànfàní láti rí ipa nínu Rumor Has It tí NdaniTV.
Ó ti jẹ́ olùkópa àṣíwájú nínu fiimu “Stuck” pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Ṣeun Àjàyí àti Lala Akindoju.[2]
Ẹ̀yà kẹfà tí MTV Shuga padà wá sí Nàìjíríà lẹ́ẹ̀kansi, wọ́n sì tún pe Aniunoh láti kópa gẹ́gẹ́ bi Cynthia lẹ́ẹ̀kansi níbi ẹ̀yà ti ọdún náà tí a pe àkọ́lé rẹ̀ ní "Choices".[3] Àwọn olùjọkópa rẹ̀ ni Timini Egbuson, Rahama Sadau, Yakubu Mohammed, Bukola Oladipupo, Helena Nelson àti Ruby Akabueze.[4]
Aniunoh tún jẹ́ ònkọ̀wé ó sì ti ní iṣẹ́ tó ti jẹ́ títẹ̀jáde. Ònkọ̀wé ará ìlu Nàìjíríà kan, Chimamanda Ngozi Adichie, sì tún ti ṣe àtúnkọ àti àtẹ̀jáde ìyọ nínu iṣẹ́ rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ n jẹ́ "Balcony".[1]