Victor Olaotan | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Lagos, Nigeria | 17 Oṣù Kejì 1952
Aláìsí | 26 August 2021 | (ọmọ ọdún 69)
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Ibadan Obafemi Awolowo University |
Iṣẹ́ | Actor |
Notable work | Tinsel |
Victor Olaotan /θj/ (17 February 1952 – 26 August 2021) jẹ́ òṣèré Nàìjíríà tí ó gbajúmọ̀ fún ipa tó síwájú tí ó kó nínú soap opera Tinsel.[1]
A bíi ní ìlú èkó, Lagos, Nigeria, ní 1952. Ó kẹkọọ ní University of Ibadan, Obafemi Awolowo University, àti Rockets University, United States.[2]
Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òṣèré nígbà tí ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèré University of Ibadan , níbi tí ó ti pàdé àwọn òṣèré míràn bíi ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Soyinka àti Jimi Solanke láàrin àwọn mìíràn. Ó di òṣèré nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹẹdogun nípasẹ̀ olùkọ́ kan tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèré Ori Olokun, ní ọdún 70's , látàrí ikú bàbá rẹ̀.[3] Lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀,ó lọ sí United States ní 1978 ṣùgbọ́n ó padà sí Nàìjíríà ní 2002 láti t'ẹ̀síwájú nínú eré rẹ̀ ní ṣíṣe. Ó gbajúmọ̀ síi ní 2013 lẹ́yìn ipa tí ó síwájú tí ó kó nínú soap opera Tinsel ti Nàìjíríà èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ lórí afẹ́fẹ́ ní oṣù kẹjọ ọdún 2008.[4] Òṣèré yìí ní ìjànbá ọkọ̀ ní oṣù kẹwa ọdún 2016 ó sì ní ìfarapa nervous system . Ó ń wa ọkọ̀ lọ sí ibùdó eré nígbà tí ìjànbá náà wáyé ní agbègbè Apple Junction, ní Festac, Èkó.
Olaotan kú ní 26 August 2021 ẹni ọdún ọ̀kan-dín-ní- àádọ́rin nípasẹ̀ ìfarapa ọpọlọ èyí tí ó wáyé látàrí ìjànbá ọkọ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ síi ní October 2016.[5]