Warona Setshwaelo | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Àdàkọ:Birth based on age as of date Gaborone |
Orílẹ̀-èdè | Botswana |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Virginia Tech |
Iṣẹ́ | Actress, video editor |
Ìgbà iṣẹ́ | 2003-present |
Warona Masego Setshwaelo (tí wọ́n bí ní ọdún 1976/1977 ) jẹ́ òṣèrébìnrin àti olóòtú fíìmù ọmọ orílẹ̀-èdè Bòtswánà.
Wọ́n bí Setshwaelo ní ìlú Gaborone, orílẹ̀-èdè Botswana, ṣùgbọ́n ó lo àwọn ìgbà ayé rẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi Ethiópíà, Swaziland, Gúúsù Áfríkà, àti Bòtswánà.[1] Ìyá rẹ̀ jẹ́ onímọ̀-ìjìnlẹ̀ nípa ìhùwàsí àwọn ènìyàn, bàbá rẹ̀ síì jẹ́ olóṣèlú tí orúkọ rẹ̀ n ṣe Ephraim Setshwaelo.[2][3] Setshwaelo lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti kàwé ni ilé-ẹ̀kọ́ gíga Virginia Tech. Ó gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ eré ìtàgé. Ó ṣiṣẹ́ atọ́kùn ètò rédíò àti olóòtù fíìmù.[4] Setshwaelo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ kópa nínu ètò Big Brother Africa ní ọdún 2003, ó síì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n fìdí rẹmi nígbẹ̀yìn níbi ètò náà.[5]
Ní ọdún 2007, Setshwaelo kó lọ sí ìlú Montreal láti tẹ̀síwájú nínu iṣẹ́ òṣèré rẹ̀.[6] Ó kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eré tó fi mọ́ Nutmeg Princess àti New Canadian Kid. Ó ní ipa kékeré kan nínu fíìmù ti ọdún 2013 tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ White House Down. Ní ọdún 2015, Setshwaelo kópa nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Waiting Room, èyí tí wọ́n ṣe ní ilé-ìṣeré Tarragon Theatre ní ìlú Toronto.[7] Ní Oṣù Kẹẹ̀wá ọdún 2015, o ́kópa gẹ́gẹ́ bi Odette nínu eré State of Denial.[8] Setshwaelo tún kópa nínu Quantico ní ọdún 2016,[9] àti ní ọdún 2018, nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ On the Basis of Sex.[10] Ní ọdún 2019, ó kópa gẹ́gẹ́ bi ìyá òṣìṣẹ́ agbófinró kan tí n ṣe Lila Hines nínu eré Bang Bang.[11]
Ó fẹ́ràn kí ó ma dáná óúnjẹ àti kí ó máa ka ìwé.[12] O ́n gbé pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ tí n ṣe Mike Payette, àti ọmọ rẹ̀ obìnrin tí orúkọ rẹ̀ n ṣe Khaya.[13]