Who's The Boss | |
---|---|
Fáìlì:Who's the Boss (2020 film) poster.jpg Promotional poster | |
Adarí | Chinaza Onuzo |
Olùgbékalẹ̀ | Chinaza Onuzo |
Àwọn òṣèré | |
Ilé-iṣẹ́ fíìmù | Inkblot Productions |
Déètì àgbéjáde | Àdàkọ:Dáàtì fíìmù |
Àkókò | Ìṣẹ́jú Àádọ́je (130 Minutes) |
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Èdè | Gẹ̀ẹ́sì |
Owó àrígbàwọlé | ₦38.5mílíọ̀nù[1] |
Ta ni Ọ̀gá náà jẹ́ fíìmù olólùfẹ́-apanilẹ́rìn-ín ọdún 2020 Nàìjíríà tó di ṣíṣejáde, kíkọ àti darí láti ọwọ́ Chinaza Onuzo (Naz Onuzo) tó ma jẹ́ fíìmù àkọ́kọ́ tó má jẹ́ Olùdarí fún.[2] Eré náà fi Sharon Ooja, Fúnké Akíndélé àti Blossom Chukwujekwu sẹ àwọn Òṣèré tó kópa Olórí. Fíìmù náà di wíwò fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọjọ́ Kẹrìndínlógún oṣù kejì, ọdún 2020 ní Èkó.[3][4][5] Fíìmù náà jáde ní tíátà ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kejì, ọdún 2020 àti tó sì rí ìròyìn gidi tó fi di àṣeyọrí ní Ọ́fíìsì tíkẹ́ẹ̀tì (box office).[6][7]
Liah (Sharon Ooja), tó jẹ́ Aláṣẹ ọdọ́ aṣojú ìgbìmọ̀ ìpolówó kan tí wọ́n kàńpá fún láti má jẹ́ kí Ọ̀ga rẹ̀ mọ̀ ìgbà tí iṣẹ́-ráńpẹ́(side hustle) rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ àti àjọ asojú náà bá gba iṣẹ́ ńlá. Nǹkan tó ti ń bàjẹ́ tẹ́lẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí ní bàjẹ́ púpọ̀ si bẹ́ẹ̀ náà dè ni arábìnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àṣeyọrí si àti wí pé kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kọ́gàá rẹ̀ mọ̀.[8]
Lára àwọn olùdásílẹ̀ Inkblot Productions, Chinaza Onuzo tí àwọn ènìyàn mọ̀ ọ́ fún aáyan rẹ̀ fún àwọn eré tó gbajúmọ̀ tó ti kọ gẹ́gẹ́ bí The Wedding Party 2, New Money àti The Set Up tó jẹ́ eré àkọ́kọ́ tó ṣe olùdarí látara rẹ̀ àti wí pé ó kéde rẹ̀ l'ori ínsíírágàmù.[9][10] Fíìmù yìí jẹ́ fíìmù Kejìlá tó ma jẹ́ ṣíṣejáde lábẹ́ bánà ṣíṣejáde Inkblot Productions.[11] Aláṣẹ vídíò ìfanilójú kékeré fíìmù jáde ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kìíní, ọdún 2020.[12][13]