Yemi Shodimu | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Ogun State, Nigeria. | 29 Oṣù Kínní 1960
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iṣẹ́ | film actor Film director and Film maker |
Gbajúmọ̀ fún | Oleku (1997) |
Yẹmí Ṣódìímú ni wọ́n bí ní Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kínní, ọdún 1960 ( January 29, 1960) ní ìlú Abẹ́òkúta ní orílẹ̀-èdè a Nàìjíríà jẹ́ eléré orí ìtàgé, Atọ́kùn Ètò, Olùdarí àti Olùgbéré jáde.[1]
Wọ́n bi ní ìlú Abẹ́òkúta, tí ó jẹ́ Olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ògùn ní apá Ìwọ̀ Oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[2]Ó lo ìgbà èwe rẹ̀ ní ìlú Abẹ́òkúta í Ààfin Ọba Aláké ilẹ̀ Ẹ̀gbá ní bi tí ó ti ní àwòfín nípa àṣà Yorùbá. [3]Ó lè sí ilé-ẹ̀kọ́ kọ́wbáfẹ́mi Awólọ́wọ́ University níbi tí ó ri gba ìwé ẹ̀rí Bachelor of Arts (B.A.) , nínú ìmọ̀ ọ̀nà ìṣeré Ìtàgé ( dramatic art) , lẹ́yìn èyí ni ó tẹ̀ síwájú ní Fásitì Ìpínlẹ̀ Èkó níbi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí Master of Arts (M.A.) nínú ìmọ̀ Mass communication.[4]
Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ ní ọdún 1976, tí ó aì kópa tó lààmì laka nínú eré orí ìtàgé tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́ Village Head Master. Ó di ìlúmọ̀ọ́ká pẹ̀lú ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olú ẹ̀dá ìtàn, ó tún jẹ́ Olú ẹ̀ ẹ̀dá ìtàn nínú eré orí ìtàgé tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́ ''' lekú''' gẹ́gè bí Àjàní nínú eré yí.[5] Túndé Kèlání ṣe adarí rẹ̀