Yvonne Jegede | |
---|---|
[[file:|frameless|alt=]] | |
Yvonne Jegede | |
Ilẹ̀abínibí | Nàìjíríà |
Yvonne Jegede jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé, olùgbéré-jáde, model àti adarí ètò lórí ẹrọ amóhù-máwòrán ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [1] Jẹ́gẹ́dẹ́ di ìlú-mòọ́ká látàrí eré kan tí ó gbé jáde tí ó pè ní 3 is Company. Ó di ẹni ayé ń fẹ́ lẹ́yìn tí ó kópa nínú fọ́rán àwo orin African Queen tí gbajú-gbajà olótin 2Face Idibia àti Annie Macaulay gbé jáde.[2]
Wọ́n bí Yvonne Jẹ́gẹ́dẹ́ ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbòn oṣù Kẹ́jọ ọdún 1983 ní agbègbè Agenebode ní Ìpínlẹ̀ Edo, ní orílẹ̀-èdèNàìjíríà . Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ati girama ní Ìpínlẹ̀.Èkó, tí ó sì tún kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nílé ẹ̀kọ́ Yunifásitì Cyprus, nínú ìmọ̀ "International Relations".[3]
Jegede bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré ní ọdún 2014 nibi tí ó ti kòpa nínú eré Missing Angels. Lẹ́yìn èyí, ó tún fara hàn nínú fọ́nrán àwo orin African Queen tí gbajúmọ̀ olórin 2Face Idibia tí wọ́n tún mọ̀ sí 2Baba gbé jáde ní ọdún 2005. Ó ti kó kópa nínú àwọn eré bíi: Okafor's Law, Single and Married, 10 Days in Sun City àti bẹ̀ẹ́ bẹ̀ẹ́ lọ. Ní ọdún 2015, ó gbé eré tirẹ̀ jáde tí ó pe àkọ́lé rẹ̀ ní 3 is Company tí ó sì kópa nínú eré náà gẹ́gẹ́ bí olú-èdá ìtàn where she starred as the lead character.[4]Ní ìparí ọdún 2016, ìwé ìròyìn ìgbàfẹ́ ti Genevieve Nnaji[5] Yàtọ̀ sí eré ṣíṣe, Yvonne Jegede ó ti fara hàn nínú fọ́nrán àwo orin "Ego" tí olórin ilẹ̀ Nàìjíríà Djinee àti fọ́nrán àwo orin Kokose tí Sound Sultan gbé jáde.