Zachee Ama Orji (tí wọ́n bí ní ọdún 1960) jẹ́ òṣèrékùnrin, olùdarí, aṣagbátẹrù fíìmù ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà[1][2] tí ó gbajúmọ̀ fún ìkópa rẹ̀ nínú fíìmù Glamour Girls, àti Blood Money. Yàtọ̀ sí eré-ṣíṣe, Orji jẹ́ oníwàásù.[3]
Zachee Ama Orji ni a bí sí Libreville, Gabon. Ó dàgbà sí ìlú Cameroon, ní Benin àti Togo, níbi tí ó ti kọ́ bí wọ́n ṣe ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Faransé dáadáa.[4] Orji kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní University of Nigeria, Nsukka, ni Ipinle Enugu . Fíìmù àkọ́kọ́ rẹ̀ jáde ní ọdún 1991, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Unforgiven Sin. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Nollywood Post pẹ̀lú Zack Orji, ó sọ bí òun ṣe gba iṣẹ́ kan láti jẹ́ olú-ẹ̀dá-ìtàn láìṣe àyẹ̀wò.[5] Láti ìgbà náà sì ni Orji ti ń kópa nínú oríṣiríṣi fíìmù àgbéléwò. Yàtọ̀ sí iṣẹ́ fíìmù ṣíṣe, ó tún jẹ́ akọrin àti oníwàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run[6]láti ìgbà tó ti ṣalábàápàdé Krístì.
Orúkọ ìyàwó Zack Orji ni Ngozi Orji, tí wọ́n sì jọ bí ọmọ mẹ́ta[7]. Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni wọ́n ń gbé.
Ní ọdún 2000, Zack Orji ṣe iṣẹ́ olùdarí àkọ́kọ́ pẹ̀lú fíìmù WEB, tí òun àti òṣèrébìnrin ilẹ̀ Ghana, ìyẹn Kalsoume Sinare náà kópa nínú rẹ̀. Fíìmù náà àmì-ẹ̀yẹ ní ayẹyẹ Ghana awards, ní ọdún 2001.
Ní ọdún 2022, Zack sọ ọ́ di mímọ̀ pé òun ń ṣe àtìlẹyìn Tinubu fún ààrẹ nínú ìdìbò ọdún 2023.[8][9]
- Living in Bondage (1992)
- Iva (1993)
- Living in Bondage 2 (1993)
- Glamour Girls[10] (1994)
- Nneka the Pretty Serpent (1994)
- Rattle Snake (1995)
- True Confession (1995)
- Brotherhood of the Darkness (1995)
- Blood on My Hands (1996)[11]
- Deadly Passion (1996)
- Glamour Girls 2 (1996)
- Silent Night (1996)
- Love in Vendetta (1996)
- Abandon (1997)
- Blood Money (1997)
- Blood Vapour (1997)
- Desperate & Dangerous (1997)
- Dead End (1997?)
- Deadly Affair II (1997)
- Garbage (1997)
- Golden Fleece (1997)
- Diamond Ring 2 (1998)
- Evil Men (1998)
- Karishika (1998)
- Sakobi 2: The Final Battle (1998)
- Witches (1998)
- Day of Reckoning (1999)
- Endtime (1999)
- The Bastard (1999)
- Asimo (1999)
- The Visitor (1999)
- Lost Hope (2000)
- Fire Dancer (2001)
- Hatred (2001)
- Late Arrival (2001)
- Mothering Sunday (2001)
- Mothers Cry (2001)
- Days of Glory (2002?)
- Bonds of Tradition (2004) (also director)
- Games Women Play (2005)
- Women's Cot (2005)
- Chameleon (2006)
- Light Out (2006)
- The Blues Kingdom (2007) (director only)
- Land of Shadow (2010) (also director)
- Head Gone (2015?)
- Brothers of Faith (2016?)
- Three Wise Men (2017)
- Code Wilo (2019)
- Our Jesus Story (2020)
- Sweet Face[12] (2020)
- Big Town[13] (2021)
- Love Castle (2021)
- Blood Sisters (2022)
- Half Of a Yellow Sun (2013)
- ↑ Adebayo, Tireni (21 October 2017). "Veteran actor, Zack Orji reveals his battle with cigarettes and Indian hemp". Kemi Filani News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 12 March 2022.
- ↑ "Zack Orji: My life as an actor, singer and preacher of God's word". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 29 February 2020. Retrieved 18 July 2022.
- ↑ "Zack Orji: My life as an actor, singer and preacher of God's word". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 29 February 2020. Retrieved 25 July 2022.
- ↑ "FALED PRODUCTION LIMITED Zack Orji". www.faledproductionlimited.com. Archived from the original on 3 March 2016. Retrieved 3 January 2018.
- ↑
- ↑ "Zack Orji: My life as an actor, singer and preacher of God's word". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 29 February 2020. Retrieved 18 July 2022.
- ↑ Orji, Sunday (30 October 2016). "I prefer singing to acting –Ngozi, Zack Orji's wife". The Sun Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 18 July 2022.
- ↑ Oyero, Ezekiel (31 July 2022). "2023: Zack Orji declares support for Tinubu". Premium Times Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2 August 2022.
- ↑ "2023: Zack Orji, wife divided along political lines as she declares support for Peter Obi". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 1 August 2022. Retrieved 2 August 2022.
- ↑ "Character I Played In Blood Sisters A Dream Role – Genoveva Umeh". Independent Newspaper Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 21 May 2022. Retrieved 18 July 2022.
- ↑ "Blood on my hands". WorldCat. Retrieved 2023-10-17.
- ↑
- ↑ "Zack Orji". IMDb. Retrieved 2 September 2021.