Àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 ní Western Sahara | |
---|---|
Àrùn | COVID-19 |
Irú kòkòrò èràn | SARS-CoV-2 |
Ibi | Western Sahara |
Ìjásílẹ̀ àkọ́kọ́ | Wuhan, China |
Index case | Boujdour |
Arrival date | Ọjọ́ kẹrin oṣù kẹrin ọdún 2020 (4 weeks) |
Gbogbo iye àwọn ẹ̀sùn | 10 (as of 26 Jun)[1] |
Active cases | 1 (titi di ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹfà) |
Iye àwọn tí ara wọn ti yá | 8 (titi di ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹfà) |
Iye àwọn aláìsí | 1 (titi di ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹfà) |
Àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 kọ́kọ́ bẹ́ sílẹ̀ ní Western Sahara ní oṣù kẹrin ọdún 2020. Àgbègbè tí orílẹ̀ èdè Morocco pàṣẹ dé ní Western Sahara nìkan ni àrùn náà wà, kò sí ní àgbègbè Western Sahara tí Sahrawi Arab Democratic Republicpàṣẹ dé .[2]
Lọ́jọ́ Kejìlá oṣù kìíní ọdún 2020 ni àjọ elétò ìlera àgbáyé, World Health Organization (WHO) jẹ́rìí pé ẹ̀rànkòrónà, Covid-19, ni ó ń fa àìsàn èémí láàárín àwọn ènìyàn kan lágbègbè Wuhan,ní Ìpínlẹ̀ Hubei, lórílẹ̀-èdè China, èyí tí wọ́n jábọ̀ rẹ̀ fún àjọ WHO lọ́jọ́ kokànlélọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 2019.[3][4]
Iye ìjàm̀bá ikú àrùn Covid-19 kéré sí ti àrùn SARS, Severe acute respiratory syndrome tó bẹ́ sílẹ̀ lọ́dún 2003,[5][6] ṣùgbọ́ rírànkálẹ̀ àrùn pọ̀ gidigidi, pẹ̀lú iye àwọn ènìyàn tí àìsàn náà pá.[7][5]
Ìlú Boujdour ni àwọn àwọn òṣìṣẹ́ àjọ ilé-iṣẹ́ kan tó wà lábẹ́ àjọ àgbáyé tí wọ́n ń pè ní [United Nations Mission for the Referendum in Western Sahara]] (MINURSO) kọ́kọ́ kéde ẹni mẹ́rin àkọ́kọ́ tí wọ́n ní àrùn náà lọ́jọ́ kẹrin oṣù kẹrin ọdún 2020.[8]
Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹsàn-án Osun kẹrin, MINURSO tún kéde ènìyàn méjì tuntun tí wọ́n tún lùgbàdì àrùn náà Dakhla, èyí tí ó mú àpapọ̀ iye àwọn tí wọ́n ní àrùn di mẹ́fà.[9]
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)