No. 9 – Bursas BSB | |||||||||||||||||||||||
---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|
Position | Forward | ||||||||||||||||||||||
League | TKBL | ||||||||||||||||||||||
Personal information | |||||||||||||||||||||||
Born | 21 Oṣù Kẹ̀wá 1985 Lagos, Nigeria | ||||||||||||||||||||||
Nationality | Nigerian | ||||||||||||||||||||||
Listed height | 1.93 m (6 ft 4 in) | ||||||||||||||||||||||
Listed weight | 80 kg (176 lb) | ||||||||||||||||||||||
Career information | |||||||||||||||||||||||
College | Virginia (2009) | ||||||||||||||||||||||
NBA draft | 2009 / Undrafted | ||||||||||||||||||||||
Medals
|
Aisha Mohammed (tí wọ́n bí ní 21 October 1985) jẹ́ agbábọ́ọ̀lù alájùsáwọ̀n ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, fún ẹgbẹ́ Bursas BSB àti Nigerian national team.
Wọ́n bí Aisha sí ìlú Ikeja, ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Bàbá rẹ̀ wá láti apá Àríwá ilẹ̀ Nàìjíríà,[1] ìyá rẹ̀ sì wá láti Ìpínlẹ̀ Edo. Ó dàgbà sí ọgbà àwọn ológun. Nígbà tí ó wà ní ọmọdún mẹ́jọ, ó kó lọ sí Keffi pẹ̀lú àọn ìdílé rẹ̀, torí wọ́n gbé bàbá rè lọ sí Keffi. Wọ́n tún lọ sí Birnin Kebbi, lẹ́yìn náà ni wọ́n wá lọ sí Port Harcourt. Bàbá rẹ̀ jẹ́ Ìmáàmù. Aisha ga tó ìwọ̀ 193cm / 6'4".[2]
Aisha jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ 'Elephant Girls'.[3] Ẹgbẹ́ náà díje dupò pẹ̀lú ẹgbẹ́ FAP side, wọ́n sì jáwe olúborí pẹ̀lú ayò 69-66 ní Maxaquene Stadium.[4] Ó gba pọ́ìntì 23 points, àti àtúnṣe mọ́kanlá láti lè borí ẹgbẹ́ 'Elephant Girls' nínú ìdíje náà.
Aisha kópa nínú FIBA Women's World Cup ní ìlú Brasil, ní ọdún 2006 àti ní ìlú Spain ní ọdún 2019; ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bó sí ìpele tó kàn. Èyí sì ló jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ ti ẹgbẹ́ ilẹ̀ Africa máa dé ìpele yẹn ní FIBA Women's World Cup, nínú ìtàn. Aisha ṣe ìrànwọ́ fún Nigeria women's national basketball team láti wọ 2004 Summer Olympics.[5] ó dẹ́kun gbígbá bọ́ọ̀lù yìí lẹ́yìn ìdíje ti 2020 Tokyo Olympics, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọ́n ba lè máa gbá bọ́ọ̀lù yìí gẹ́gẹ́ bí òun náà ti ń gbá a.