Amanda Black

Amanda Black
Background information
Orúkọ àbísọAmanda Benedicta Antony
Ọjọ́ìbí24 Oṣù Keje 1993 (1993-07-24) (ọmọ ọdún 31)
Mthatha, Eastern Cape, South Africa
Irú orin
Occupation(s)
  • Singer
  • songwriter
Years active2015–present
Labels
Associated acts

Amanda Benedicta Antony (tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù keje, ọdún 1993), tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Amanda Black,[1] jẹ́ olórin ti orílẹ̀-èdè South Africa àti òǹkọrin. Ìlú Gcuwa ni wọ́n bi si, ibẹ̀ ló sì dá̀gbà sí pẹ̀lú. Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olórin bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1999, nígbà tí ó wà ní ọmọdún mẹ́fà, níbi tí ó ti ń kọ orin ní ilé-ìjọsìn. Amanda jẹ́ ọ̀kan lára àọn olùdíje Idols South Africa apá kọkànlá.[2] Black kó lọ sí ìlú Johannesburg ní ọdún 2016 láti tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ orin kíkọ rẹ̀. Ó tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn pẹ̀lú Ambitiouz Entertainment ní ọdún 2016, ó sì di ìlúmọ̀ọ́ká ní ọdún kan náà lẹ́yìn tí ó ṣàgbéjáde orin àdàkọ rẹ̀, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Amazulu",[3] èyí tí wọ́n yàn fún àmì-ẹ̀yẹ lóríṣiríṣi. Àwo-orin àkọ́kọ́ rẹ̀, ìyẹn Amazulu (2016), mu kí ó gba àmì-ẹ̀yẹ lóríṣiríṣi bíi "Àwo-orin tó dára jù lọ fún ọdún náà", "Best Newcomer of the Year," "Best Female Artist of the Year" àti "Best R&B Soul/Reggae Album".[4] Ní ọdún 2019, ó di olórin tí àwọn ènìyàn ń gbọ orin rẹ̀ jù lọ ní orí Apple Music.[5]

Àwo-orin Amanda kẹta, èyí tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́, Mnyama jáde ní ọdún 2021. Lẹ́yìn náà ni ó ṣá̀gbéjáde orin àdákọ méjì, tí àkọ́lé wọn ń jẹ́; "Kutheni Na" àti "Let It Go".

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Amanda Benedicta Antony jẹ́ Xhosa.[6] Ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù keje, ọdún 1993 ni wọ́nbi, sí ìlú Mthatha, Eastern Cape, ní South Africa, ó sì dàgbà sí ìlú Butterworth, Eastern Cape, níbi tí ó ti lo ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀. Bákan náà ni ó gbé ní East London. Ó kó lọ sí Port Elizabeth, níbi tí ó ti parí ètò-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ ní Kabega Christian School, Port Elizabeth, kí ó ṣẹ̀ tó wá tẹ̀síwájú ní Nelson Mandela Metropolitan University, níbi tí ó ti kékọ̀ọ́ nípa Ẹ̀kó.[7]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Nkwanyana, Fundiswa (13 December 2016). "I always knew I'd be famous – Amanda Black". The Citizen. South Africa. Retrieved 21 May 2017. 
  2. "Top 5 Idols SA contestants with successful music careers". Archived from the original on 19 May 2022. Retrieved 11 October 2021.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "Songstress Amanda Black releases new single Amazulu". South African Broadcasting Corporation. 16 October 2016. Archived from the original on 10 October 2017. Retrieved 21 May 2017.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. Bambalele, Patience. "Amanda Black proves her star power". Sowetan LIVE. Retrieved 28 May 2017. 
  5. Samanga, Rufaro (16 August 2019). "In Conversation with Amanda Black: 'I've grown incredibly from the girl who wrote 'Amazulu' - OkayAfrica". OkayAfrica. 
  6. TshisaLIVE. "Amanda Black: I once believed that being black wasn't cool". Times LIVE. Retrieved 28 May 2017. 
  7. Bambalele, Patience. "Amanda Black proves her star power". Sowetan LIVE. Retrieved 21 May 2017.